Bàbá arúgbó tó fipá bá ọmọ ọdún mẹ́rìnlá lòpọ̀ l'Ọ̀yọ́ dèrò ẹ̀wọ̀n - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Tuesday, August 3, 2021

Bàbá arúgbó tó fipá bá ọmọ ọdún mẹ́rìnlá lòpọ̀ l'Ọ̀yọ́ dèrò ẹ̀wọ̀n


Ile ẹjọ Majisireeti to wa niluu Ibadan ti sọ pe ki baba agbalagba ẹni ọgọta ọdun kan, Baṣiru Ajadi ṣi maa gbatẹgun lọgba ẹwọn Abolongo to wa niluu Ọyọ titi digba ti igbẹjọ ẹsun ifipabanilopọ ti wọn kan an yoo fi waye.
 
Ọmọdebinrin, ọmọ ọdun mẹrinla kan ta a forukọ bo laṣiri la gbọ pe baṣiru fipa ba lopọ lagbegbe Aba Alade, Ọlọrunṣogo, niluu Ọyọ.  
 
Agbẹjọro ọlọpaa, Gbemisọla Adedeji to fẹsun kan Baṣiru niwaju ile-ẹjọo sọ pe nnkan bi aago meje alẹ, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu to ṣẹṣẹ kọja yii tan ọmọdebinrin naa wọnu yara rẹ, nibi to ti fipa ba a laṣepọ.
 
Onidajọ S. H. Adebisi nigba to n sọrọ sọ pe ọgbọn ọjọ, oṣu kẹjọ ti a wa yii ni igbẹjọ yoo waye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI