Sunday Igboho lẹtọọ lati jaye ori ẹ labẹ ofin - Ile-ẹjọ yẹyẹ Malami ati ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, August 4, 2021

Sunday Igboho lẹtọọ lati jaye ori ẹ labẹ ofin - Ile-ẹjọ yẹyẹ Malami ati ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ


Il-ẹjọ giga tipinlẹ Ọyọ, eyi to wa niluu Ibadan lonii ti sọ pe adajọ agba lorilẹ-ede Naijiria, Abubakar Malami ati ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ orilẹ-ede yii ko lẹtọọ lati mu Oloye Sunday Adeniyi Adeyẹmọ ti ọpọ awọn eeyan tun mọ si Sunday Igboho.


Onidajọ Ladiean Akintọla lo sọ eyi di mimọ loni, Ọjọru, Wẹsidee, bẹẹ lo tun sọ pe Malami ati ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ko lẹtọọ kankan labẹ ofin lati maa wa Sunday Igboho kaakiri, bi ko ṣe pe ki wọn fi silẹ lati jaye ori ẹ labẹ ofin.
 
Nibẹ lo tun ti sọ pe wọn ko lẹtọọ kankan lati gbẹsẹ le owo Sunday Igboho to wa nile ifowopamọ, bẹẹ ni wọn ko gbọdọ maa fi ẹtọ rẹ dun un labẹ ofin orilẹ-ede yii.

Idajọ yii waye pẹlu ẹjọ ti agbẹjọro rẹ, Yọmi Aliu pe lori ọrọ naa. Lẹyin igbẹjọ yii ni Onidaajọ Akinọla sọ pe wọn o gbọdọ dẹruba a, wọn o gbọdọ halẹ mọ ọn, wọn o gbọdọ ti i mọle, bẹẹ ni wọn ko gbọdọ pa a, bẹẹ ni wọn ko gbọdọ gbẹsẹ le oṣunwọn owo rẹ ni banki.

Wọn ni o lẹtọọ ati aṣẹ lati rin, ko si yan fanda gẹgẹ bii ọmọ orileede yii, wọn ko si gbọdọ ṣakọlu kankan si ile rẹ.

Gbogbo aọn ti won gbọ idajọ yii ni wọn fo fayọ, ti wọn si n kan saara si ileeṣẹ eto idajọ fun idajọ aiṣegbe lẹyin ẹnikan yii.

Idajọ yii waye pẹlu bi agbẹjọro rẹ, Alli ṣe gba ile-ẹjọ lọ lẹyin ti wọn ṣakọlu si ile rẹ niluu Ibadan lọjọ ki-in-ni, oṣu keje ọdun yii, ti wọn si ba ọpọlọpọ nnkan jẹ. 
 
Biliọnu marun-un naira lo beere fun lori iwa ti ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ hu yii.
Onidajọ naa wa a sun igbẹjọ mi in siwaju di ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹjọ ti a wa yiiu

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI