Digbí lara mi yá, kò sí ikú kan lójú mi - Ọlaiya sọ̀rọ̀ jáde - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, August 2, 2021

Digbí lara mi yá, kò sí ikú kan lójú mi - Ọlaiya sọ̀rọ̀ jáde


Gbajugbaja ogbontarigi oṣere tiata nni, Ẹbun Oloyede ti ọpọ awọn eeyan tun mọ si Ọlaiya Igwe ti sọ pe digbi lara oun wa, ko si nnkan to ṣe oun, bẹẹ loun ko ṣaisan.

Ana, ti i ṣe Aiku, Sannde ni awọn kan gbe iroyin naa sori ikanni ayelujara ti fesibuuku wi pe Ọlaiya ti jade laye, ati pe aisan kidinrin lo ṣeku pa a.

Ọmọbìnrin kan to pe orukọ rẹ ni Temitọpẹ Love lo gbe iroyin ofege naa sita lori fesibuuku, koda, to sọ pe lẹyin ti wọn ṣiṣẹ abẹ fun un tan ni ọsibitu UCH to wa ni Ibadan lo jade laye.

Ṣugbọn nigba to n tako iroyin naa lati ẹnu ọkan lara awọn to sunmọ ọn daadaa, Ọgbẹni Leke, ti awọn eeyan tun mọ si Ṣeyi Crown sọ pe iroyin ẹlẹjẹ lasan ni.


Nigba to n ba AWIKONKO sọrọ lori foonu rẹ, Ṣeyi Crown sọ pe ko si nnkan to ṣe Ọlaiya, ati pe digbi lara rẹ wa, lai ni aisan kankan lara.

O lawọn ti wọn n fẹ fi iroyin naa jẹun ni wọn gbe e jade, eyi to sọ pe ko bojumu to fun iwa ọmọluabi.

Bẹẹ lo gba gbogbo eeyan lamọran wi pe ki wọn ma ṣe gba iroyin naa gbọ rara, nitori pe ayederu pọmbele ni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI