Mi ò rí nǹkan ìdùnnú nídìí iṣẹ́ orin mọ́, ó ti ń yọ kúrò lọ́kàn mi - Kollington Àyìnlá pariwo síta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, August 2, 2021

Mi ò rí nǹkan ìdùnnú nídìí iṣẹ́ orin mọ́, ó ti ń yọ kúrò lọ́kàn mi - Kollington Àyìnlá pariwo síta


Bi ẹ ba pe e ni Baba Alatika, Kebe-n-Kwara, Baba Alagbado, ẹni kan ṣoṣo naa lẹ n peri rẹ, agba ọjẹ ati ogbontarigi to sọ iṣẹ orin kikọ di faaji fawọn eeyan ni Alaaji Kolawole Ayinla ti ọpọ awọn eeyan mọ si Kollington Ayinla. Agba olorin Fuji yii lo ba ikọ AWIKONKO lalejo nile ẹ laipẹ yii, nibi to sọ oriṣiriṣi nipa iṣẹ Fuji ati ipo ti Fuji wa, bẹẹ lo tun sọrọ nipa idi to fẹẹ fiṣẹ orin Fuji silẹ. Ẹ ka ohun to ba Ọlaide Ọṣinuga ati Yetunde Ṣoyọye sọ.
 
 
Ipo wo gan an ni orin Fuji wa lasiko yii?
Ipo daadaa ni Fuji wa, ko si le pare lailai. Orin Fuji ko l’afiwe, ko si ni alatako tori pe gbogbo awọn to n kọ orin bi i takasufee, iyẹn hiphop kan n f’ẹsẹ halẹ l’asan ni, inu orin Fuji ni wọn ti n mu orin ti wọn n kọ. 
 
Agba olorin to n fawọn nnkan to ba n ṣẹlẹ lawujọ kọrin lati maa fi gba awọn eeyan, paapaa ijọba lamọran ni yin. Ki lo de ti ẹ dakẹ lasiko yii pẹlu bi ijọba ṣe n fi ara ni araalu lasiko yii. Abi ko han si i yin ni?
Ọmọ ti a ba n ba sọrọ, to ba n gbọ, a tubọ ma maa ba a sọ ọ ni, ṣugbọn eyi ti a ba n ba sọrọ to jẹ pe tinu ẹ lo n ṣe, a ni lati fi sipo rẹ ni. Mi o nilo lati maa tun da ara mi laamu. A ti sọ ọ titi, a ti pariwo laimọye igba, ẹyin eti wọn lọrọ wa n gba kọja, ṣe lo tiẹ tun wa n bajẹ si i ni bayii. Mi o ro pe a ti i pade iru ijọba yii ri. Ijọba ki wọn maa paayan lojoojumọ, ki wọn maa ji eeyan gbe lojoojumọ. Awọn nnkan to n ṣẹlẹ yii n jẹ ki ẹru ile aye maa ba wa. ‘Say Baba, Say Buhari’ ni wọn n pariwo tẹlẹ, ṣugbọn ko sẹni to tun le sọ bẹẹ mọ bayii, afi ti wọn ba tun maa sọ pe ‘No Baba, No Buhari’. Wọn ko mu inu wa dun, imọ tara wọn ṣaa nikan ni wọn mọ. Mi o wa mọ iru ẹṣẹ ti a ṣẹ wọn, a maa duro ninu oorun ati ojo titi lati d’ibo fun wọn ni, sibẹsibẹ naa, wọn ko mu ori wa wu. Eyi to ba ranti dupẹ ni, pupọ ninu wọn ni wọn ki i ranti dupẹ. Ko si nnkan to ni ibẹrẹ ti ki i lopin, to ba jẹ pe a n gbadun ni, yoo dopin lọjọ kan, iya ti wọn fi n jẹ wa yii na ni ibẹrẹ, bẹẹ si lo maa dopin lọjọ kan. Wọn ko ṣe daadaa rara, a ko gbọdọ tan ara wa jẹ.

Abacha ta n sọ pe o buru nigba naa ko ran awọn eeyan sita lati maa paayan kaakiri bayii, ko si ni kẹnikẹni maa bẹ eeyan lori kiri, ṣugbọn ebi to n pa wa lasiko yii ju ti asiko Abacha lọ. Afi bi a ba n tan ara wa jẹ, ijọba yii ko ṣe daadaa rara. O ṣe wa a jẹ pe asiko yii ni gbogbo nnkan gbe owo lori. Ebi n pa wa gidigidi, bawọn ba si maa sọrọ bayii, ọrọ bi wọn ṣe maa ti awọn ẹnubode pa ni wọn ma maa tẹnumọ. Nnkan ti ẹ ko ni, ti wọn n ko wọle fun un yin lẹ n sọ pe ki wọn ti ẹnubode pa. Ọlọrun ri gbogbo ẹ. 
 
 
Njẹ orilẹede yii ṣi ni ọjọ iwaju rere gẹgẹ oju ti ẹ fi wo o?
Mo fi Ọlọrun ṣe ẹlẹrii, mi o le sọ nnkankan nipa ẹ pe bi ọjọ iwaju yoo ṣe ri ree. Ko ye wa mọ rara. 
 
Ipo wo lẹyin wa lori idaduro ilẹ Yoruba?
Ipo ti gbogbo eeyan ba wa naa ni mo wa. Igba ti a wa ni iṣọkan, ṣe a ri ojutuu ara wa ni, ti a tun wa n sọ pe ka pin. Nigba ti a ba n sọ pe Ijẹbu ko le ṣe e, Abẹokuta ko le ṣe e, Ọyọ ko le ṣe e, ta lo wa fẹẹ ṣe e? Yoruba lo bajẹ ju ninu gbogbo ẹya to wa lorilẹede yii. Ẹnu kan ṣoṣo lawọn ti wọn n dari wa lasiko yii ni lẹnu, bẹẹ lawọn Ibo naa ni ọrọ kan ṣoṣo lẹnu, ṣugbọn awa Yoruba gan an ni iṣoro, ọrọ ẹyin ko jẹ ka ri ojutu si iṣoro ti a ni. Nigba ti a ba jokoo ipade, ti a fi ẹnu ko lori nnkan, to wa di pe a ko ti i dide kuro nibi ipade naa ti a tun ti n sọ nnkan mi in, igba wo la wa fẹẹ ṣe iyẹn da gan an? Girama tawọn oyinbo gan an ko le tumọ rẹ lo wa lẹnu Yoruba. Oyinbo ka-n-ka ni wọn n sọ, ti wọn ko si ṣe amulo rẹ.

Ko ma jẹ pe Yoruba gan an lo n da Naijiria yii laamu, a ti gbọn ju ara wa lọ, ọgbọn agbọnju naa lo si n da wa laamu. Ẹ lọ wo awọn to n ṣakoso wa, ipo nla wo lẹ ri ti ki i ṣe pe mọla tabi Hausa ẹgbẹ wọn lo wa nibẹ? Ki lo de ti wọn ko fi Yoruba tabi Ibo sibẹ? Ṣebi Naijiria kan naa la sọ pe a jọ wa? Awọn n da ṣe ile aye tiwọn lọtọ, awa n da ṣe ti wa jakujaku. Yoruba ki i ran ara wọn lọwọ. Ṣe awa ti a ki i ran ara wa lọwọ le da duro ni?

Iwa wa ko le da duro. A ko ni iwa to le da duro, amọ o n wun wa ka da duro, ṣugbọn eṣu to wa lẹyin ọrun wa, to n ti wa kaakiri ko le jẹ ka duro. Ti wọn ba ri ododo ọrọ nilẹ, wọn ki i ba ara wọn sọ ọ. Ko si nnkan to dara to ka da duro, amọ ki la fẹẹ fi bọ ara wa? Ṣe ka jẹ ara wa lẹsẹ yii naa la fẹ maa tẹle? Awọn kan sọ pe Aolẹ lo ṣepe fun Yoruba, ko ni itunmọ kankan rara.
 
Ẹ wo ẹgbọn wa to ja fitafita fun wa, ẹni to tun gbe apoti ibo, to si wọle, ti gbogbo aye ri i, Yoruba kan naa yii lo lọ ba Babangida pe ko gbọdọ gbe ipo naa fun un, ki lo tun ku ti a fẹẹ sọ? Ẹya buruku to to wa ko si. 
 
Ki lẹ wa le sọ pe o jẹ iṣoro Yoruba gan an ti ẹnu wọn ko fi ko?
Mi o le dahun ẹ, tori pe awọn kan sọ pe Alaafin Aolẹ lo ṣepe fun Yoruba ti ọrọ ẹnu wa ko fi ko. Ta lo mọ nnkan ti wọn ṣe fun un? Ṣe ọrọ ẹnu Yoruba ko ni? Yoruba buru gan an ni. Wọn ni oro ma sọko, o ni eyi toun mu dani yii, oun a ṣi sọ ọ na. Ẹni to ba leti ko gbọ ni, ẹni to ba si loun ko gbọ, iṣoro tiẹ ni, ṣugbọn o ti wa ninu akọsilẹ pe mo sọ ọ. Mo kọ orin kan lọdun kan pe ‘Bi mo ba ranti pe ọmọ Yoruba ni mi, oju a gba mi ti. Awọn to ti n ṣ’ọga lọjọ to ti pẹ, ẹ wa t’ori owo, ẹ wa sọ ara yin d’ẹru, ẹ o ni nnkan ni o, ẹ jẹ lọ ọ ṣe ijiroro k’ori yin pe. Ṣebi ẹ ri Hausa bi wọn ṣe n duro ti ara wọn, ‘ṣe bi ẹ ri Ibo bi wọn ṣe n duro ti Ibo. Ẹyin ara wa, ẹ ma tori ẹgunjẹ ki ẹ gbagbe Oduduwa...’. 

Yoruba ko le gbọrọ lailai. Bi Hausa ba bi ọmọ silu Oyinbo lonii, ede Hausa yẹn naa lọmọ yii maa sọ, ko si iye iwe to le wu ki ọmọ Hausa ka laye, ede wọn lo maa sọ. Bi Ibo ba bimọ lonii si ibikibi lagbaaye, ede wọn ko ni i kuro lẹnu ọmọ wọn. Ṣugbọn Yoruba ti wa nkọ? Amọju, igberaga, ka sọ pe a to nnkan ti a ko to lo n da wa laamu. Awa funra wa la tun ma maa sọ pe ọmọ wa ko gbọdọ sọ ede Yoruba lẹnu, nigba ti a ba n pe ede abinibi wa ni fanakula, ẹ o ri i pe wahala nla lo wa fun wa? 
 
Oriṣiriṣi nnkan to n ṣẹlẹ ni Naijiira, paapaa ilẹ Yoruba lẹ ti fi kọrin sẹyin lati fi gba awọn eeyan pẹlu ijọba lamọran, bawo lo ṣe maa n ri lara yin pe dipo ki ayipada wa, ṣe ni iwa ibajẹ tun n peleke si i?
Ibanujẹ nla lo maa n jẹ fun mi. Ti m ba n ranti awọn orin ti mo ti kọ sẹyin, ti mo si ri i pe nnkan ti mo fi kọrin nigba naa tun ṣi n ṣẹlẹ, inu mi ki i dun rara. O kan maa n ba mi lọkan jẹ pe gbogbo ariwo ti mo pa ninu orin mi, ṣe ni wọn tun n tẹramọ iwa ibajẹ. Ẹnu kan ṣoṣo yii naa la ni, ṣugbọn ka panupọ lati sọrọ ni nnkan ti Yoruba ko ni. A fi ki wọn maa lo ede ti wọn n pe ni ‘Divide and Rule’ fun wa, ki wọn si maa tan wa jẹ. Bi Yoruba ba ti ri owo, ṣe ni wọn maa tẹle wọn lọ. A ko lee da duro lati da  aṣẹ pa, afi ka maa wa ẹni ti a maa tẹle lẹyin kiri. Ibi abini ko ṣe e yago fun ni, Yoruba ki i ṣe ẹya to dara rara.

Ọlẹ ni wa, a ko le ja, ẹnu lasan la ni. Hausa pẹlu Ibo nikan ni wọn lagbara, faari ati faaji ti ko nitumọ la n ṣe kiri. Ka jaye, ka muti la wa fun. 
 
Awọn kan sọ pe ko le si idibo lọdun 2023. Ti idibo ba tiẹ wa a pada ṣẹlẹ, njẹ ẹ ro pe ko le logun ninu?
A dibo 2011, ko ni ogun ninu; a dibo 2015, ko si la ogun lọ; bẹẹ naa la tun dibo 2019, ko si ba ogun kankan de, ti 2023 naa ko le yatọ rara, ko si ogun kankan to fẹẹ ṣẹlẹ. Yoruba ko le ja, ẹnu lasan la ni. Idibo 2023 ko le dogun kankan. 
 
 
Njẹ ẹ tiẹ ṣi le kọrin fawọn oloṣelu bi i ti tẹlẹ mọ?
Awa naa ni oṣelu. Ile aye ti laju ti atijọ lọ, ko si ipaniyan laye atijọ, ṣugbọn ki n kan to o ṣẹlẹ lasiko yii, wọn a ti sọ pe ki wọn lọ pa ẹnikan. A fi ki Ọlọrun ṣaanu wa. 
 
Ki lawọn iriri yin nidii iṣẹ orin ti ẹ yan laayo?
Ọmọ Yoruba ni wa, orin Yoruba naa la n kọ, iwa Yoruba naa la si ma maa wu, ti a si ma maa binu ara wa. Awọn baba nla wa ti wọn ti kọrin sẹyin, bawọn naa ṣe kọ ọ niyẹn. Orin ọtẹ ni wọn kọ, ohun ti ẹran ba jajẹ naa lọmọ rẹ maa jẹ ninu ẹ. Nnkan ti a ba n’iwaju naa la n ṣe e. Oriṣiriṣi iriri la ti ba pade nidii iṣẹ yii ti ko ṣe e ka tan. 
 
Njẹ orin yii tiẹ ti figba kan ri fẹẹ yọ lọkan yin?
O tiẹ ti wa n yọ lọkan bayii, tori mi o fẹẹ ri nnkan idunnu kankan nibẹ mọ bayii. Iru awọn ọmọ to n jade lẹyin wa naa, radarada ni wọn n ṣe kiri. Ko si iyatọ latigba ti a ti n ba a bọ. Gbogbo ba a ṣe n pariwo latigba yii wa, ibi pẹlẹbẹ naa ni ọbẹ wa n fi lelẹ. 
 
Ija agba to n ṣẹlẹ lagboole Fuji dinku lasiko yii, ko si ariwo lọtun-losi mọ, bawo lo ṣe ṣẹlẹ. Ṣe nipasẹ yin ni?
Ọlọrun lo ba wọn yọnju ẹ, Ọlọrun lo ko si wọn ninu ti wọn fi jokoo jẹ. Mo ti da si i laimọye igba, mo si dupẹ lọwọ Ọlọrun pe opin ti de ba gbogbo rogbodiyan naa. Mo tiẹ tun sọrọ wọn ninu rẹkọọdu ti mo ṣẹṣẹ ṣe kọja yii wi pe ki wọn ye e ba ara wọn ja. Wọn ti  ni owo, wọn si tun ti lokiki, ki wa ni wọn n wa kiri, ki ni wọn tun n fẹ? 
 
Bawo lẹ ṣe wa a bẹrẹ orin Fuji nigba naa?
Bi wọn ṣe n bẹrẹ naa ni mo ṣe bẹrẹ lati kekere. Lọdun naa lọhun, mo ti sọ ọ ri laimọye igba, idi iṣẹ ṣọja ni mo wa lọdun naa lọhun pẹlu ekeji mi to ti ku, Sikiru Ayinde Barrister, ki Ọlọrun tubọ maa ba mi fori jin in. Barrister lo wa ba mi pe ki n jẹ ka pada sidi iṣẹ orin wa, tori pe owo ti wọn n san fun wa nigba naa kere. Mo ni nibo lo ti ri ṣọja to kọrin ri, wi pe a maa pẹ lẹwọn bi wọn ba gba wa mu. O ni ọgbọn la maa fi ṣe e. Bo ṣe kuro lọdọ mi l’Abẹokuta niyẹn, to wa si Eko lati ṣe igbaradi. Igba to pada de lo sọ pe oun ti ṣetan lati kọrin, mo si lemi ko ti i bẹrẹ, ọdun 1968 si 1969 ni ọrọ ti mo n sọ yii. 

Ọwọ ti wọn fi mu wa ni baraaki Abẹokuta igba naa ko to di pe wọn tu u ka, eeyan ko ni fẹẹ ṣiṣẹ ṣọja rara nigba naa. Igba to ya, o sọ pe ki n kọ lẹta wi pe wọn maa fun mi laaye lati maa ji gbogbo awọn eeyan loru lati jẹ saari ati lati gbadura, emi naa kọ ọ, wọn si bu ọwọ lu lẹta naa fun mi, bi mo ṣe bẹrẹ niyẹn. Ṣugbọn ko to to asiko yẹn, nigba ti mo wa ni kekere, iwe iroyin Morning Post to jẹ ti Oloogbe Nnamddi Azikwe nigba naa maa n kọ nipa mi pe “10-year-Old Kollington Ayinla”, igba yẹn ni mo gba ife ẹyẹ ti Nnamdi Azikwe, ekeji mi gba ife ẹyẹ ti Coca-Cola ni Evans Square l’Ebute Mẹtta, ipinlẹ Eko.

A maa n ji wọn lasiko Saari ninu aawẹ Ramadaani ni lai mọ pe nnkan to maa wa pada gbe wa jade bayii ni. Barrister maa n wa ba mi, ti a jọ ma maa jade kọrin were kiri ni, ko to di pe emi lọ ọ darapọ mọ ṣọja, ti mo si tun fa oun naa wọnu ṣọja. Ẹka orin ni mo wa l’Abẹokuta, emi ni mo n fun feere, ṣugbọn Barrister lo lọ soju oogun, igba to de lo wa sọ gbogbo nnkan ti oju ẹ ri nibẹ fun mi. Mo dupẹ pe ọrẹ mi to lọ soju oogun ko ku sibẹ, emi naa ko si ku si baraaki, tori pe pupọ lo n ku si baraaki, ki i ṣe awọn to n lọ soju ogun nikan. 
 
Awọn ayipada wo lo deba iṣẹ ṣọja lasiko yii si tigba ti ẹ fi wa ninu ẹ?
Ko si ibẹru mọ ninu iṣẹ ṣọja bi i tigba ta a wa ninu ẹ. 1960 si 1990, ibẹru ṣi wa daadaa nigba yẹn. Ibẹru ṣi wa lasiko yii naa ṣugbọn ko to ti gbogbo igba ti emi fi wa nibẹ. Boya ki n sọ pe tori awọn asiko naa jẹ asiko ogun ni. Ko sẹni to to bẹẹ lati rin gberegbere wọ baraaki ṣọja bo ṣe wu, ọlọpaa gan an ko le wọbẹ lai ki i ṣe pe o ni nnkan pataki to fẹ wa a ṣe nibẹ, ibẹru yẹn wa. 
 
Njẹ ọmọ yin kan tiẹ wa nidii iṣẹ ṣọja?
Mi o ni ọmọ nibẹ rara o, mi o si le gba ki ọmọ mi ṣe ṣọja. 
 
Ki lo fa a?
Mi o kan fẹ ni. Mo ni ọmọ kan to wa ninu iṣẹ aṣọbode. 
 
Gbogbo igba lẹyin pẹlu ọrẹ yin, Oloogbe Sikiru Ayinde Barrister fi maa n ja nigba aye wọn. Bi ẹ ba pari ija lonii, ẹ maa tun bẹrẹ ija lọjọ keji. Ki lo maa n da awọn ija yii silẹ gan an?
Boya ki n sọ pe orogun owo la fi n ṣe ni, tabi ki n sọ pe eremọde ni. Bi i ka maa gba bọọlu si ara wa ni mo le pe e. Ọjọ kan la jọ n jẹun nile mi, ibi ti a ti n jẹun naa lo ti sọ pe ‘Kọla, ṣe o mọ pe bi a ṣe n jẹun yii, awọn kan n lu ara wọn n’igboro nitori ti wa?’. Ọrẹ timọtimọ lemi atiẹ, mi o si le gbagbe ẹ lailai. Awọn eeyan ko le mọ bi a ṣe n ṣere to ni gbogbo igba ti a fi n kọrin eebu sira wa. Ọja lasan la fi n ta, nnkan ti wọn si n pe ni ọpọlọ itaja niyẹn. 
 
Oloogbe Barrister kọrin pe awọn gba oye Dọkita Fuji, ko pẹ lẹyin naa gbe rẹkọọdu jade wi pe ẹ ti di Purofẹẹsọ. Ki lo fa a?
Mo fi n tako Barrister nigba naa ni, mo n jẹ ko mọ pe oye temi gba ju tiẹ lọ, lara awọn aṣiri orogun owo si ni. 
 
Njẹ ẹ tiẹ maa n ni imọlara wi pe Barrister ko si laye mọ?
Nigba ti mi o ki i ṣe igi. Aimọye igba ni mo ma fi n la ala, ti a si maa n ṣere loju ala yẹn. Wọn ni ko da keeyan maa la iru ala bẹẹ. Lati kekere lo ti maa n wa ba mi ni Apapa Road. Mushin loun n gbe nigba naa, o ju mi lọ daadaa, ṣugbọn ọrẹ timọtimọ ni wa nigba aye ẹ. Bi iya tabi baba eeyan ba ku, teeyan wa n la ala ri, iyẹn ko sọ pe kẹni naa ku lọjọ keji.

Gbogbo igba ti Oloogbe Ayinla Ọmọwura ba n ba olorin kan ja lẹ ma fi n wa lẹyin ẹ. Ajọṣepọ wo lo wa laarin yin nigba naa?
Ẹgbọn mi ni wọn tori pe mo kere si wọn gan an, igba ti mo wa da orin Fuji silẹ ni mo ṣẹṣẹ tun wa fi Ayinla Ọmọwura ṣe oludamọran pataki fun ẹgbẹ orin mi. Ọta pọ fun Ayinla nigba naa, wọn si lẹni ti a ba sun ti la maa n jarunpa lu. Pupọ awọn eeyan lo fẹran Ayinla Ọmọwura gidi nigba aye ẹ, ṣugbọn awọn ti ko fẹran rẹ ninu olorin naa pọ. Igba ti ẹgbọn mi Olowonyọ naa bu Ayinla titi, emi ni sọ pe ki wọn jẹ ki n lọ fun Olowonyọ l’esi ọrọ wọn. 
 
Ẹgbọn mi Ayinla fi mi rẹrin nigba ti mo sọ bẹẹ wi pe ọrọ wo lo wa lẹnu mi ti mo fẹẹ fi bu Olowonyọ, igba ti mo ṣe rẹkọọdu naa jade tan, ti Ayinla gbọ ọ, iyalẹnu nla lo jẹ fun wọn. Wọn ni ṣe pe mo le sọ iru ọrọ bayii, wi pe ọrọ ti mo sọ naa ti pọ ju. Mo kan maa n rẹrin bi mo ba n ranti awọn iṣẹlẹ igba naa ni, ṣugbọn ka dupẹ lọwọ Ọlọrun. 
 
Ki lawọn ẹkọ ti ẹ ri kọ lara Oloogbe Ayinla Ọmọwura?
Ẹkọ ti mo ri kọ ko ju pe ẹgbọn mi maa n wo aṣọ gidi gan an, wọn maa n mura tonitoni, wọn si maa n na owo fawọn eeyan. Bi Ayinla ba wọ ile ọti, o maa ra ọti fun gbogbo eeyan to ba wa nibẹ. Emi naa nigba kan, bi mo ba n jade lọ, mo maa n da owo silẹ fawọn ọmọ kekeeke. Mo kọ ẹkọ aṣọ wiwọ ati ki n maa na owo fawọn eeyan. 
 
O ti le logoji ọdun Ayinla Ọmọwura ti lọ, njẹ ẹ tiẹ ṣi maa n ṣe iranti wọn?
Bawọn mọlẹbi ba sọ fun mi, o di dandan ki n ko ipa t’emi nibẹ. Bi ki n sọ pe mọlẹbi kan naa ni wa ni, tori pe a sunmọ ara wa gidi gan an nigba aye ẹ. A jọ n wọ yara igbohunsilẹ lati ṣe rẹkọọdu ni. Igba mi in, tori orin Ayinla, mi o ki i raaye lọ si baraaki lọ ṣiṣẹ ṣọja ti mo yan laayo, ṣe ni mo maa n tẹle e lẹyin kaakiri, mo si kere gan an nigba yẹn. 
 
Awo orin tiẹ ti kọ ti to meloo bayii?
O ti pọ rẹpẹtẹ o, mi o le ka wọn tan bayii o. Igba kan ti mo ka awo orin mi gbẹyin, marunlelọgọrun-un (105) ni. 
 
Ewo lẹ kọ to fẹ ba ariyanjiyan tabi ipenija de?
Bi iṣẹ ṣe gbọdọ maa wa niyẹn. Orin teeyan ba kọ, ti ko ba si ariyanjiyan nibẹ, ki i dun rara, ko si le ta. Ṣugbọn ti ariyanjiyan ba wa nibẹ, awọn eeyan a sọ oriṣiriṣi nipa ẹ. Meloo ni mo fẹẹ ka ninu orin to ba ariyanjiyan de ti mo kọ? Wọn pọ , ṣugbọn mo dupẹ lọwọ Ọlọrun. 
 
Kollington nigba to wa lẹnu iṣẹ ṣọja
 
Ewo lẹ kọkọ gbe jade nigba yẹn?
Iṣẹju mẹta pere ni mo fi kọ ọ, ‘Gbegbe a gbohun mi dẹnu’, ẹlẹẹkeji ni ti eyi ti mo fi bu Olowonyọ. 
 
Ewo ninu awọn rẹkọọdu yii lo wa gbe e yin jade?
Onipako ni, orin yẹn ni mo fi gbeja Ayinla Ọmọwura, rẹkọọdu keji ti mo maa ṣe si ni. 
 
Awọn aṣa bi i Kasabubu, Lalakukulala, Ọmọge Sango, Baba Alatika atawọn mi in lẹ mu wọnu iṣẹ orin Fuji, nibo lawọn aṣa yii ti n wa nigba yẹn?
Mi o le sọ pato, idi ni pe mi o niṣẹ meji ju orin lọ, mo gbọdọ wa nnkan ti aye maa fi tẹwọ gba ti orin ti mo ba gbe jade ni. Mi o ni ironu meji kọja ki n kọrin, oriṣiriṣi ironu ati imisi lo n wa. Ko si nnkan ti mo le maa ṣe lọwọ, ẹbun orin yii a kan maa sare wa ni, koda bi mo ba wa ni baluwẹ tabi ile igbọnsẹ. Igba to ya ni mo lọ ra kinni kekere ti wọn fi n gba ohun silẹ, eyi tawọn oloyinbo n pe ni midget. Bi imisi orin ba ti wa, maa sare fi ohun orin naa sinu midget naa ki n ma ba a gbagbe. Iṣẹ orin ko rọrun rara o. 
 
Njẹ awọn aṣa naa ṣi ku, abi agba ti gba a ni?
Wọn ṣi pọ rẹpẹtẹ, ko si le tan lailai, ẹbun Ọlọrun ni. 
 
Awọn eeyan nigbagbọ pe bi ẹ ṣe le kọrin ki awọn eeyan naa lẹ tun le kọrin bu eeyan, ṣe loootọ ni?
Meji-meji lọrọ ile aye. Bi oke ṣe wa la ni isalẹ, ba a ṣe ni ọtun naa la ni osi. Bo ṣe wa niyẹn. 
 
Njẹ awọn orin yin igba yẹn ṣi dabi awọn ti ẹ n kọ lasiko yii?
Gbogbo igba yẹn, oju ko ti i la bi ti asiko ta a wa yii. Bi aye ṣe n ri la n tọ ọ. Wọn ti ba iṣẹ orin jẹ pẹlu awọn nnkan ti wọn fi n gbọ orin lasiko yii. Bi orin kan ba jade lonii, bi eeyan kan ṣoṣo ba ti ni i, gbogbo eeyan ti ni i niyẹn, tori pe ṣe ni wọn maa n pin in fun ara wọn. Redio kekere ti wọn n pe ni Bluetooth ni wọn fi n gbọ orin lasiko yii, nnkan to si ba iṣẹ orin jẹ niyẹn. Wọn ko jẹ kawọn makẹta maa ri ounjẹ jẹ mọ bi i tigba kan. Awọn makẹta ti wọn ti gbe wa jade laye atijọ ni wọn ti jẹ eere rẹpẹtẹ, ti wọn ti ti ara wa kọle. Ko si makẹta to maa n fẹ ko owo nla sori orin mọ lasiko ta a wa yii. Ko ma dabi ẹni pe wọn ko ṣiṣẹ ni nnkan tawọn makẹta asiko yii n ṣe. 
 
Njẹ ọjọ iwaju rere tiẹ wa fawọn to ṣẹṣẹ n dide bọ nidii iṣẹ orin Fuji?
Nnkan ti wọn ba ba naa ni ki wọn maa ṣe. Orin ti wa a gba yẹyẹ debi pe gbogbo eeyan lo fẹ maa kọrin bayii. Olorin lo fẹẹ pọ ju ninu gbogbo awọn oṣiṣẹ Naijiria, ati ẹni to n kọrin gidi, ati ẹni to n kọ ikọkukọ, olorin naa ni gbogbo wọn. Aisi iṣẹ si lo jẹ kawọn eeyan sọ ara wọn di olorin ojiji. Ọlọrun si tun n fi alubarika si awọn olorin takasufee, iyẹn hiphop, bi wọn ṣe n fo soke, ti wọn n jan ara wọn mọlẹ naa lawọn ololufẹ wọn n tẹle wọn, owo si tun ti wa nibẹ fun wọn. 
 
Bawo lẹyin pẹlu Alaaja Salawat Abẹni tiẹ ṣe pade gan an?
Ọrọ aarin emi atiẹ niyẹn, ko yẹ ki n maa sọ ọ jade. Ọmọ mẹta la bi fun ara wa. Ibi iṣẹ orin yii naa la ti pade ni Stadium Hotel. O maa n wa woran ni, ti m ba kọrin diẹ, maa sọ pe koun naa wa a kọrin nigba naa. Iyawo mi n kọrin daadaa. 
 
Ki lo fa a ti ẹ ko fi jọ gbe papọ nigba naa?
A ko ti i fẹ ara wa sile nigba naa. Igba to ya la ṣẹṣẹ pada ṣe igbeyawo. Ibẹ la ti bẹrẹ si i kọrin ifẹ papọ. 
 
Bawo wa ni ajọṣepọ yin bayii?
A ṣi sọrọ titi nigba to n ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọta ọdun, ọjọ keji naa, a tun rojọ titi. Iyawo mi ṣi ni, arẹwa mi ṣi ni. Ẹni to bimọ mẹta fun mi, ki lo tun ku? 
 
Ṣe loootọ ni pe bi olorin ko ba ti i mu nnkan tabi fa nnkan, imisi orin ki i wa?
Nnkan ti wọn fi ṣe ipilẹṣẹ ti wọn niyẹn. Emi o mọ nnkan fa, mi o si mọ nnkan mu. Igba ti mo ṣi wa ni kekere ni mo ti mu ọti gbẹyin. Wọn ni ọpọlọ mi ko gbe ọti mimu nigba naa lo jẹ ki n jawọ, ki n si to o bẹrẹ orin rara ni. Ti mo ba mu ọti, ti mo de ile, mo maa n ba awọn iyawo mi ja ni, igba ti ọti naa ba da loju mi ni wọn a ṣẹṣẹ maa sọ pe emi ni mo jẹbi, eyi lo jẹ ki n gbe e ju silẹ. Iwa ọmọde ni gbogbo ẹ nigba yẹn. 
 
Bawo lo ṣe maa n ri lara yin bi ẹ ba ranti awọn igba kekere yin?
Wọn ni beeyan ba wa lọmọde, a maa ṣebi ọmọde, bo ba si dagba, o maa ṣebi agba naa ni. Gbogbo iwa ti mo hu ni kekere lo maa n pa mi lẹrin-in bi mo ba n ranti wọn. Bawọn ọmọ mi baa n ṣe awọn nnkan ti mo ti ṣe ni kekere, ti wọn n ba wọn wi, emi ni mo maa n sọ pe ki wọn fi wọn silẹ tori pe ọmọde ni wọn. Wọn ko kuku mọ pe emi naa ti ṣe iru ẹ ri ni kekere. Mo si dupẹ lọwọ Ọlọrun pe bi mo ṣe bimọ to pọ to, ko si eyi to ya tọọgi ninu wọn. 
 
Ọmọ yin meloo lo gbegba orin bi i ti yin?
Abigbẹyin emi pẹlu Salawa Abẹni ni. Orin takasufee loun si n kọ. BigCheff lawọn ololufẹ rẹ si n pe e. Inu mi maa n dun pe ọmọ mi. 
 
Ajọṣepọ wo lo wa laaarin ẹyin at’awọn ọba ilẹ Yoruba?
Gbogbo ọba ilẹ Yoruba ni ọba wa, mi o wa lati idile ọba, iwọnba ni ma maa toju bọ ile ọba kiri, yatọ si Ọba Gbadewọlu, Alawowo tilu Awowo nipinlẹ Ogun. Aburo mi ni, o fẹran mi, emi naa si fẹran ẹ. 
 
Bawo ni irin ajo orin kikọ loke okun ṣe bẹrẹ?
‘A lulu l’Amẹrika, Oyinbo gbajo o. Akata yari, wọn lawọn fẹẹ fẹ Kebe...Salawa ko gba pe ki wọn fọkọ oun, ni Salawa ba yari...’ Ilu oyinbo dara ju ti wa lọ. Awọn ọmọ Yoruba ti wọn wa nibẹ lo n gbe wa larugẹ. Ọdọ ẹnikan ti a n pe ni Alaka ni mo kọkọ lọ ni London lọdun naa lọhun. Alaka yii lo kọkọ gbemi wọ London, lẹyin ẹ ni mo tun lọ s’Amẹrika ati bẹẹbẹẹlọ. 
 
Njẹ ẹ tiẹ ṣi le rin irin ajo oke okun bi i ti tẹlẹ mọ bayii?
Mi o fẹ maa lọ sibẹ mo bayii, tori pe mo ti ni ibẹru fun ọkọ ofurufu. Nnkan ti ki i ba mi l’ẹru tẹlẹ lo ti wa a di ibẹru nla fun mi bayii. Ti ọkọ baluu ba kọja nibi ti mo ba wa, ẹru maa n ba mi ni pe ṣe nnkan temi naa maa n wa ninu ẹ ree to jẹ pe ko si nnkan to duro le lori. Bi aṣiṣe kan ṣoṣo ba ṣẹlẹ bayii, iku ni fun gbogbo awọn to ba wa ninu ẹ. Mo maa n ki awọn to n wọ ọkọ baluu ni. Awọn ọmọ mi maa n binu sira wọn bayii ni pe mi o yọju si wọn. Oriṣiriṣi irọ ni mo n pa fun wọn nipa idi ti mi o fi le lọ ba wọn nilu oyinbo naa mọ.
 
Boya tori pe mo ṣi kere nigba naa ni aya mi ki i ṣe e ja ti m ba wa ninu ẹ ni, ṣugbọn ni bayii ti agba ti n de, ẹru nla lo maa n ba mi fun ọkọ ofurufu. Ilu oyinbo maa n wun mi lati lọ, ṣugbọn ti ọkọ baluu yii naa ni iṣoro ti mo ni. Ka dupẹ lọwọ awọn oyinbo ti wọn jẹ ka maa ri ara wa nipasẹ ọkọ baluu, ṣugbọn ṣaa, ki wọn f’ọwọ mu nnkan wọn. 
 
Iṣẹ to gba wahala ati asiko ni iṣẹ orin kikọ jẹ, bawo lẹ ṣe n fun ara n’isinmi?
Ko rọrun rara, tori pe bi a ṣe n kuro l’Ekoo, la n lọ si Kaduna, bẹẹ la tun n lọ Abuja ati kaakiri agbaye, ki i ṣe iṣẹ to rọrun rara, ṣugbọn Ọlọrun lo n fun wa ni isinmi. Bi a ba lọ kọrin nibomi in bi ilu Ilọrin, ẹsẹ mi a ti wu soke ti a ba maa fi bọ silẹ ninu mọto, a si tun maa kọrin, oore ọfẹ Ọlọrun ni o. Mi o ro pe mo maa fẹ maa raaye fun iṣẹ orin kikọ yii mọ. O ti to ki n lọ fẹyin ti bayii. Mi o fẹ mọ boya iṣẹ orin ṣi pe tabi ko pe mọ, ṣugbọn nnkan ti mo mọ daju ni pe mo ti ba iṣẹ orin kikọ de ibi to ni apẹẹrẹ rere. 
 
Ọjọ wo ni inu yin dun ju nidii iṣẹ yii?
Bi i igba teeyan ba ta puulu, to si jẹ ni bi mo ba ṣe rẹkọọdu jade, tawọn eeyan si ra a gidi, iyẹn to bọ si itẹwọgba awọn eeyan. Inu mi maa n dun gidi. 
 
Ọjọ wo lẹ le sọ pe inu yin bajẹ ju?
Ko si ọjọ to ba mi ninu jẹ ju ọjọ ti Sikiru Ayinde barrister ku lọ. A ṣi sọrọ nigba to ku ọsẹ meji ko ku, mo lọ ba a lọsibitu lọjọ naa, ti a si sọrọ titi. Ṣe lo sọ fun mi pe ki n maa gbadura foun. O sọ awọn ti maa lọ dupẹ lọwọ ẹ fun mi, iyẹn awọn to dide iranlọwọ fun un. A jọ sunkun gidi lọjọ naa, igba ti mo ri i kẹyin niyẹn. Lati ọsibitu naa ni wọn ti gbe e lọ si Germany, lati Germany lọ si London, ko to jẹ pe London naa lo ku si. O ba mi lọkan jẹ gidi. 
 
Kin lamọran yin fawọn to ṣẹṣẹ n dide bọ nidii iṣẹ orin Fuji?
Ki wọn kọju si iṣẹ naa, iyẹn to ba jẹ pe orin ni wọn fẹ maa kọ o. Ki wọn kọ orin gidi, ki wọn si fi ọpọlọ kọ ọ debi ti aye maa tẹwọ gba a. Orin ti ọmọde ati agba maa le gbọ ni ki wọn kọ. Ki wọn si ma ṣe ba ara wọn ja. 
 
Ki ni kawọn eeyan maa reti lati ọdọ yin laipẹ?
Ki wọn maa reti nnkan to ba dun, to si dara. Laipẹ lo si maa jade.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI