Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun ni iroyin ti fi to wa leti pe o ti padanu baba re, Ọmọwe Emmanuel Adesanya Abiọdun lojiji.
Ẹni ọdun mọkandinlaadọrun-un (89) ni baba naa jẹ ko to di pe o jade laye lonii, ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ keji, oṣu kẹjọ, ọdun 2021.
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ, wọn ni o ti ṣe diẹ ti baba naa ti wa lori idubulẹ aisan, ko to di pe ẹlẹmi gba a.
Aisan ọjọ ogbo la gbọ pe o ran Ọmọwe Emmanuel Adesanya Abiọdun lọ sọrun.
Baba yii ti ọpọ awọn eeyan mọ si Baba Tiṣa, jẹ ọmọ bibi ilu Ipẹru-Rẹmọ, ipinlẹ Ogun.
Ọmọwe Abiọdun fi iyawo, awọn ọmọ, ati awọn ọmọ ọmọ silẹ saye lọ, eyi to daju pe oku rẹ ki i ṣe oku ọfọ rara.
Gbogbo ohun ti wọn n ṣe laye ni baba yii ṣe ko to o ku, bẹẹ ni Ọlọrun tun kẹ ẹ debi pe ọmọ rẹ, Dapọ Abiọdun jẹ gomina, bẹẹ lawọn yooku naa wa ni ipo gidi loriṣiriṣi ẹka iṣẹ ti wọn yan laayo.
No comments:
Post a Comment