Haruna tó fẹ́ẹ́ sọ odindi ìlú kan sínú òkùnkùn ayérayé ti há o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Sunday, August 1, 2021

Haruna tó fẹ́ẹ́ sọ odindi ìlú kan sínú òkùnkùn ayérayé ti há o


Ọrọ ti wọn ni Jesu sọ gbẹyin lori igi agbelebu wi pe 'o pari' ni wọn lo jade lẹnu Haruna Muhammed, ọmọ ọdun mọkandinlọgbọn nigba tọwọ palaba rẹ segi  laipẹ yii.

Wọn ni ṣe ni Haruna lọọ ji awọn waya tuntun ti wọn fi ṣe ina mọnamọna si agbegbe Mubi, ipinlẹ Adamawa

A gbọ pe awọn waya naa ni wọn fi mu ina wọ agbegbe Maiha, Mubi ati  awọn agbegbe to sunmọ wọn.

Agbẹnusọ fawọn ọlọpaa ipinlẹ naa, Suleiman Nguroje to gbe iroyin naa si wa leti sọ pe ọjọ Ẹti, Furaidee to kọja yii niṣẹlẹ ọhun.

O ni ki i se Haruna nikan lo lọ ṣiṣẹ buruku naa, bi ko ṣe pe mẹta ni wọn, ṣugbọn yo jẹ pe pun nikan lọwọ tẹ.

Siwaju si i lo sọ pe ọga awọn, AliyuAdamu ti paṣẹ pe ki iwadii tubọ tẹsiwaju, ki ọwọ ba a le tẹ awọn yooku lati foju wọn ba ile ejo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI