Ìjọba Kwara fẹ́ẹ́ gbógun ti àrùn kọ́lẹ́rà tipátipá - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, August 24, 2021

Ìjọba Kwara fẹ́ẹ́ gbógun ti àrùn kọ́lẹ́rà tipátipá


Ijọba ipinlẹ Kwara lawọn ti ṣetan lati gbogun ti ajakalẹ arun kọlẹra kaakiri ipinlẹ naa, ki awọn araalu le wa ni igbaye-gbadun ninu imọtoto ati alaafia.
 
Ẹka ileeṣẹ ijọba Kwara, iyẹn Kwara State Environmental Protection Agency, KWEPA, lo sọ eyi di mimọ laipẹ yii, ti wọn si ni alaafia araalu lo jẹ awọn logun pupọ.
 
Wọn ni gbogbo awọn nnkan to le da wahala silẹ lago ara lawọn ṣetan lati ṣe abojuto wọn lai fi akooko ṣofo.

Alakoso ileeṣẹ naa, Alaaji Saad Ayuba Dan-Musa lo sọrọ yii, to si ni gbogbo awọn ohun to le ṣakoba fun awọn agbegbe, eyi ti yoo mu ki arun naa tan kalẹ lawọn fẹẹ gbogun ti patapata.
 
Ijọba ibilẹ Moro ni Alaaji Dan-Musa ti sọrọ yii nibi ayẹwo ti wọn ṣe lọ sibẹ, eyi ti wọn fi n ṣe iwadii awọn agbegbe to nilo abojuto ni kiakia.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI