UBEC ṣetán láti kọ́ ilé-ẹ̀kọ́ ìgbàlódé 'Smart School' sipinlẹ Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, August 24, 2021

UBEC ṣetán láti kọ́ ilé-ẹ̀kọ́ ìgbàlódé 'Smart School' sipinlẹ Kwara


Ajọ kan to n ṣagbatẹru eto ẹkọ, Universal Basic Education Board [UBEC] lawọn ti ṣetan lati ṣagbatẹru kikọ ile ẹkọ igbalode 'Samrt School' sipinlẹ Kwara.
 
Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq la gbọ pe o ṣokunfa bi ajọ UBEC ṣe fẹẹ kọ ile-ẹkọ igbalode naa sipinlẹ ọhun, fun anfaani awọn akẹkọọ lati jẹ anfaani eto ilana ẹkọ igbalode.
 
Ṣaaju asiko yii la gbọ pe UBEC ti bu ọwọ lu kikọ iru awọn ile-ẹkọ igbalode bayii sawọn ipinlẹ Ogun lorilẹ-ede yii, iyẹn lọdun 2019, ṣugbọn ti ko si ipinlẹ Kwara ninu wọn latari bi wọn ṣe sọ pe wọn ko kun oju oṣuwọn to.
 
Agbeyẹwo eto ẹkọ laaarin ọdun 2013 si 2019 ti ajọ UBEC wo nipinlẹ naa ni ko jẹ ki wọn le bu ọwọ lu kikọ ile-ẹkọ igbalode yii, ṣugbọn ni kete ti wọn bẹrẹ si i ri awọn ayipada rere, wọn lawọn ṣetan lati kọ ọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI