Ikunlẹ abiyamọ o! Arọda ojo ṣọṣẹ buruku l'Ondo, ọpọ dukia lo tun ṣofo danu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, August 21, 2021

Ikunlẹ abiyamọ o! Arọda ojo ṣọṣẹ buruku l'Ondo, ọpọ dukia lo tun ṣofo danu


Ibanujẹ nla lopin ọsẹ ti a wa yii jẹ nilu Ikarẹ-Akoko, ijọba ibilẹ Akoko North, ipinlẹ Ondo nigba ti wọn sọ pe ojo arọrọda ba dukia olowo iyebiye jẹ, to si sọ pupọ awọn eeyan di alainile lori.
 
Egbẹẹgbẹrun miliọnu naira ni dukia ta a gbọ pe agbara bajẹ kọja sisọ, to si mu kawọn eeyan maa bu sẹkun gidigidi.
 
Fun bi wakati marun-un gbako la gbọ pe ojo ọhun fi rọ, to si ṣan agbara nla gidi kaakiri ilu Ikarẹ-Akoko, nibi to ti ba dukia rẹpẹtẹ jẹ kọja sisọ.
 
AWIKONKO gbọ pe odo nla kan to gbajumọ daadaa, iyẹn odo Dada kun dẹmudẹmu, to si bo opopona mọlẹ, koda, gbogbo ile ati ṣọọṣi to wa nitosi odo yii ni agbara bo mọlẹ, ti ko si sẹni to ri wọn mọ, afigba ti agbara naa bẹrẹ si i ṣan lọ, lẹyin ti ojo naa da.
 
Wọn ni mọto, ọkada atawọn to n fẹsẹ rin ko le kọja si odikeji ileeṣẹ ijọba kan to wa lagbegbe Agbaluku, koda, gbogbo awọn ti wọn n rin irin ajo ni agbara yii da duro fun ọpọlọpọ wakati. 
 
Nigba to n sọrọ, alakoso ileeṣẹ to n ri sọrọ eto ayika nipinlẹ Ondo, Arabinrin Yẹmisi Adeniyi kanminu gidi lori iṣẹlẹ naa, to si ni ọpọ igba ti iru ojo bayii ba ti rọ lawọn eeyan maa n padanu dukia wọn. 
 
O wa gba awọn eeyan lamọran wi pe ki wọn dẹkun lati maa kọ ile sẹgbẹ odo, tabi ibi ti wọn ri i pe o lewu fun alaafia wọn, paapaa bi iru awọn iṣẹlẹ yii ba n ṣẹlẹ. Bakan naa lo gbawọn araalu lamọran lati yee da ilẹ ati idọti sinu odo mọ, ki wọn le dẹkun omiyale, agbara ya ṣọọbu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI