E fara jin fun iṣẹ yin - Kọmiṣanna fọrọ eto ẹkọ gbawọn oṣiṣẹ lamọran - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Saturday, August 21, 2021

E fara jin fun iṣẹ yin - Kọmiṣanna fọrọ eto ẹkọ gbawọn oṣiṣẹ lamọranKọmiṣanna fọrọ eto ẹkọ ati idagbasoke ọmọniyan nipinlẹ Kwara, Hajia Saadatu Modibbo Kawu ti gba gbogbo awọn oṣiṣẹ patapata lẹka eto ẹkọ lamọran lati gbajumọ iṣẹ ti wọn gbe le wọn lọwọ, bẹẹ si ni ki wọn fara jin fun iṣẹ ti wọn gbe le wọn lọwọ.
 
O ni ki ri i pe wọn n tete de ibi iṣẹ wọn lasiko to yẹ, ki wọn si jẹ ki ijafafa ati titẹpa mọṣẹ jẹ akọmọna wọn loore-koore.
 
Kawu lo gbawọn oṣiṣẹ naa lamọran nibi ipade to ba wọn ṣe l'Ọjọru, Wẹsidee, ọsẹ yii.
 
O ni ijọba yii nilo wọn lati tẹpa-mọṣẹ, ati pe bi wọn ba ṣe tẹpa mọṣẹ to ni yoo jẹ ki ijọba ipinlẹ Kwara mu awọn ipinnu ati ileri rẹ ṣẹ fawọn araalu, eyi ti yoo fawọn olokoowo nla-nla lati wọle.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI