Kò tíì sọ́bà bíi Ṣàngó nínú ìtàn Aláàfin Ọ̀yọ́ - Ọba Adéyẹmí pariwo síta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, August 22, 2021

Kò tíì sọ́bà bíi Ṣàngó nínú ìtàn Aláàfin Ọ̀yọ́ - Ọba Adéyẹmí pariwo síta


Alaafin Ọyọ, Iku Baba Yeye, Alayeluwa, Ọba Lamidi Adeyẹmi kẹta ti sọ pe titi di akooko yii, ko tii si ọba to da bi Ṣango ninu itan awọn ọba to n jẹ Alaafin niluu Ọyọ.
 
Ana, Satide, Abamẹta ni Ọba Adeyẹmi sọrọ naa nibi aṣekagba ayẹyẹ ọdun Ṣango agbaye tọdun 2021 to waye.
 
Nibẹ lawọn arinrin-ajo-afẹ ati awọn alejo ti peju-pesẹ lati wo bo ṣe lọ si.
 
Alaafin Ọyọ sọ pe bawọn ṣe n daabo bo aṣa ati iṣe ti pọn dandan, fun anfaani awọn iran to n bọ lẹyin, ki aṣa ati iṣẹṣe ma baa parun lojiji.
 
Nigba to n sọrọ nipa Ṣango, Ọba Adeyẹmi sọ pe lakooko ti Ṣango wa ni ipo Alaafin, o lagbara, o si lawọn ẹbun nla pẹlu awọn iwa to jẹ ko da yatọ si awọn to ti jẹ ko too depo, atawọn to jẹ lẹyin rẹ.
 
O ni ọdun meje gbako ni Ṣango fi jẹ oye Alaafin ko to di pe o yi pada di oriṣa akunlẹbọ.
 
Siwaju si i ni Kabiyesi sọ pe ọkan pataki lara awọn ọdun to gbajugbaja kaakiri agbaye ni Ṣango, to si ni gbogbo aye ni wọn ti tẹwọ gba a, eyi ti wọn si fi n gbe aṣa ati iṣe Yoruba larugẹ.
 
Bẹẹ lo wa gba awọn ọmọ ati olugbe ilu Ọyọ lamọran lati maa gbe ni irẹpọ, alaafia ati iṣọkan, ati pe ki wọn ma ṣe gbagbe aṣa ati iṣẹṣe ti wón fi tẹ ilẹ Yoruba do.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI