Àwọn méjì dèrò àtìmọ́lé lórí ẹ̀sùn jìbìtì l'Ondo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, August 22, 2021

Àwọn méjì dèrò àtìmọ́lé lórí ẹ̀sùn jìbìtì l'Ondo


Ọwọ awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo mọkumọku lorilẹ-ede yii, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC ti tẹ awọn gendekunrin meji kan nipinlẹ Ondo.

Ilu Akurẹ la gbọ pe ọwọ ti kọkọ tẹ ọkan lara wọn lori ẹsun wi pe o n lu jibiti ori ayelujara, ti awọn eeyan tun mọ si Yahoo-Yahoo.
 
Ẹnikeji la gbọ pe ọwọ tẹ oun naa niluu Akurẹ la gbọ pe o pe ara rẹ ni onimọ-ẹrọ, to si lawọn ileeṣẹ ori ayelujara to ti n lu awọn eeyan ni jibiti.
 
A gbọ pe ṣe ni wọn kọkọ gbe wọn ya ni teṣan ọlọpaa ẹkun ‘A’, ko to di pe wọn ko wọn lọ silu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ lati lọ fọrọ wa wọn lẹnu wo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI