Lẹyin ibalopọ gbigbona! Lauretta pa 'Suga Dadi' rẹ danu, o ji miliọnu meje naira ati mọto Benz rẹ gbe salọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, August 5, 2021

Lẹyin ibalopọ gbigbona! Lauretta pa 'Suga Dadi' rẹ danu, o ji miliọnu meje naira ati mọto Benz rẹ gbe salọ


Ko si iroyin kayeefi meji to n tan kaakiri ori ikanni ayelujara lakooko yii, to yatọ si ti ọdọmọbinrin ti ẹ n wo yii, Lauretta, ẹni ti wọn loo pa ọkan lara awọn baba alaye rẹ, iyẹn Suga Dadi (Sugar Daddy) rẹ danu.
 
Yatọ si pe Lauretta pa ọkunrin naa ti wọn pe ni Chukwumeka danu, o tun ji miliọnu meje naria ati mọto bọginni, Mercedes Benz 4matic rẹ gbe salọ.
 
Ipinlẹ Akwa Ibom lọhun la gbọ pe iṣẹlẹ yii ti waye lọsẹ to kọja yii.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn lo ti ṣe diẹ ti Lauretta ati ọkunrin naa, Chukwuemeka ti n fẹ ara wọn, koda, ti wọn ni ọkunrin naa ti sọ pe oun yoo fẹ ọlọmọge yii niṣu-lọka gẹgẹ bi iyawo.
 
Young woman allegedly stabs her boyfriend to death in Akwa Ibom, flees with his Mercedes Benz and N7m  
AWIKONKO gbọ pe lọjọ ti Lauretta maa pa ọkunrin naa danu, ko pẹ ti wọn ni ibalopọ gbogbona tan, ti Ckukwuemeka gbagbe sun lọ, ni wọn sọ pe Lauretta yọ ọbẹ, to si gun un pa.
 
Bo ṣe gun un pa tan, lo ko owo rẹ to jẹ miliọnu meje naira, bẹẹ lo tun gbe mọto Benz 4matic naa, koda, gbogbo iwe mọto yii lo palẹ rẹ mọ, ko to na papa bora.
 
Awọn ọrẹ Chukwuemeka la gbọ pe wọn kofiri rẹ ninu agbara ẹjẹ, ti wọn si lọ fiṣẹlẹ ọhun to awọn ọlọpaa leti. Latigba naa la gbọ pe wọn ti bẹrẹ si i wa Lauretta kaakiri.
 
Young woman allegedly stabs her boyfriend to death in Akwa Ibom, flees with his Mercedes Benz and N7m  
Nigba ti wọn sọ pe aṣiri maa pada tu, ibi ti wọn ni Luaretta ti n ṣe faaji ara rẹ nile igbafẹ kan, la gbọ pe awọn ọlọpaa ti pada ri i, pẹlu mọto to ji gbe salọ.
 
AWIKONKO gbọ pe mọto naa ni wọn fi tọpinpin Lauretta de ibi ti aṣiri rẹ ti tu.
 
Wọn ni Lauretta ti yi orukọ iwe mọto naa pada si ti ara rẹ, bẹẹ lo tun ti gba awọn iwe to yẹ, eyi to le fidi rẹ mulẹ wi pe oun gan-an lẹni to ni i, lai mọ pe ọkunrin naa ti ṣe awọn nnkan to le tu aṣiri ibi ti mọto naa ba wa.
 
Ẹni to gbe iroyin naa sita, Ọgbẹni Vincent Aluu, sọ pe ọmọ ọlọpaa ni Lauretta, ati pe Ogoja, nipinlẹ Cross River ni baba rẹ ti n ṣiṣẹ ọlọpaa.
 
Teṣan ọlọpaa Ewet to wa ni Akwa Ibom la gbọ pe ọmọbinrin naa wa, nibi ti wọn ti n fọrọ wa a lẹnu wo.
 
Young woman allegedly stabs her boyfriend to death in Akwa Ibom, flees with his Mercedes Benz and N7m  
Young woman allegedly stabs her boyfriend to death in Akwa Ibom, flees with his Mercedes Benz and N7m

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI