Delta ni Onọmẹ ti wa n jale n'Ibadan kọwọ to tẹ ẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, August 7, 2021

Delta ni Onọmẹ ti wa n jale n'Ibadan kọwọ to tẹ ẹ


Lọjọ Eti, Furaidee ana, nileeẹ alaabo Sifu Difẹnsi kede wi pe ọwọ awọn ti tẹ afurasi ọdaran kan, Onọmẹ Samuel, ọmọ ọdun mọkanlelogun nigboro ilu Ibadan.
 
Omọ bibi ipinlẹ Delta ni wọn pe Onọmẹ tọwọ tẹ yii, ta a si gbọ pe wọn gba ibọn ilewọ kan lọwọ ẹ, lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu to kọja.

Agbegbe Olomi Academy to wa niluu Ibadan, ipinlẹ Oyọ lọwọ ti tẹ ẹ.
 
Nigba to n sọrọ, ọa Sifu Difẹnsi nipinlẹ Oyọ, Michael Adaralewa sọ pe Onọmẹ pẹlu awọn ọrẹ rẹ mẹta ni wọn jọ n jale kaakiri Ibadan, ṣugbọn to lawọn yooku rẹ ti salọ.
 
Owo ati dukia la gbọ pe wọn n fi ibọn naa gba lọwọ awọn eeyan. Awọn to salọ naa ni Sọdiq ati Tọheeb, ilu Ikorodu, nipinlẹ Eko la gbọ pe awọn ti wa n jale.
 
Onọmẹ sọ pe ẹgbẹrun lọna aadọta naira loun ra ibọn naa, pẹlu erongba lati maa fi jale
 
Adaralẹwa ti wa a sọ pe igbesẹ ti n lọ lat foju ẹ ba ile ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI