Nítorí ọ̀rọ̀ ààbò tó péye, ìjọba Kwara ṣèpàdé àlàáfíà pẹ̀lú àwọn olórí Fulani - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, August 31, 2021

Nítorí ọ̀rọ̀ ààbò tó péye, ìjọba Kwara ṣèpàdé àlàáfíà pẹ̀lú àwọn olórí Fulani


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lọjọ Aje, Mọnde ana ti ṣe ipade alaafia papọ pẹlu awọn olori ẹya Fulani to n gbe nipinlẹ naa, ki ọrọ eto aabo le tubọ kẹsẹjari.
 
Gbogbo awọn agbaagba atawọn alẹnulọrọ laaarin awọn ẹya Fulani nipinlẹ Kwara la gbọ pe wọn wa nibi ipade ọhun, nibi ti ijọba ti gba wọn lalejo lati jọ sọ asọyepọ.
 
Nibẹ ni ijọba ti fi da wọn loju wi pe gbogbo awọn ẹya Fulani to n gbe nipinlẹ Kwara ni yoo jẹ anfaani eto aabo to peye lai ni idiwọ tabi idaamu kankan ninu.
 
Gbogbo awọn olori awọn ẹya Fulani kaakiri ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa nipinlẹ naa la gbọ pe wọn wa nibi ipade alaafia yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI