Kìí ṣe dandan láti gba abẹ́rẹ́ Kòrónà - Adájọ́ pàṣẹ fún Obasẹki àti ìjọba Ẹdo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, August 31, 2021

Kìí ṣe dandan láti gba abẹ́rẹ́ Kòrónà - Adájọ́ pàṣẹ fún Obasẹki àti ìjọba Ẹdo


Ile-ẹjọ giga tijọba apapọ to wa niluu Port-Harcourt, ipinlẹ Rivers ti paṣẹ fun Gomina Godwin Obasẹki tipinlẹ Ẹdo, ati ijọba ipinlẹ naa wi pe ko gbọdọ fi dandan fun awọn ọmọ ipinlẹ rẹ ni abẹrẹ korona.
 
Onidajọ Stephen Dalyop nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ sọ pe kii ṣe dandan lati gba abẹrẹ to n dena ajakalẹ arun korona, ati pe ẹni to ba wu lati gba a ni ko gba a.
 
Bẹ o ba gbagbe, lọsẹ to kọja yii ni Gomina Ọbasẹki sọrọ naa niwaju awọn akọroyin wi pe o ti di dandan fun gbogbo awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Ẹdo lati gba abẹrẹ to n dena arun korona, ati pe ẹni to ba kọ lati gba a yoo foju winna ofin.
 
Eyi lo mu ki awọn kan dide lati gbe ijọba ipinlẹ naa, ati Gomina Ọbasẹki lọ siwaju ile-ẹjọ, lati da Gomina ọhun lọwọ kọ wi pe ko tete ko ọrọ rẹ jẹ nipa wi pe kawọn eeyan lọ gba abẹrẹ naa ni tipatipa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI