Ó ṣẹlẹ̀ o! Àwọn tọ́ọ̀gì yawọ 'Radio Nigeria' n'Ibadan, wọ́n ba dúkìá olówó iyebíye jẹ́ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, August 1, 2021

Ó ṣẹlẹ̀ o! Àwọn tọ́ọ̀gì yawọ 'Radio Nigeria' n'Ibadan, wọ́n ba dúkìá olówó iyebíye jẹ́


Ṣe lọrọ di boo lọ o yago lọna lanaa, ọjọ Abamẹta, Satide nigba ti wọn lawọn tọọgi yawọ gbajugbaja redio kan lorilẹ-ede yii, iyẹn Radio Nigeria to wa niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ.
 
Redio naa ti wọn tun n pe ni Amuludun 99.1 FM la gbọ pe awọn tọọgi ti ko din ni mejila yawọ lọsan ana, ti wọn si bẹrẹ si i ba gbogbo awọn dukia to wa nibẹ jẹ.
 
Bo tilẹ jẹ pe titi dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yii tan la ko ti i le sọ pato idi tawọn tọọgi naa fi yawọ redio yii, ṣugbọn ta a gbọ pe, oriṣiriṣi nnkan ija oloro bi aake, ada, ọbẹ, atawọn mi in ni wọn ko lọ sibẹ.
 
 
Ọdun mẹwaa le diẹ sẹyin ni wọn da redio yii silẹ, to si ti gbayii kaakiri igboro ilu Ibadan ati agbegbe ẹ.
 
AWIKONKO gbọ pe dukia to le ni obitibiti miliọnu naira ni wọn bajẹ kọja sisọ.
 
 
Lara awọn dukia ti wọn bajẹ ni ferese, mọto loriṣiriṣi, awọn irinṣẹ atawọn nnkan mi in. 
 
Ọgbẹni Niyi Dahunsi, nigba to n sọrọ sọ pe otitọ ni, ati pe awọn agbofinro ti wa lori iṣẹlẹ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI