Ọkàn mi balẹ̀ lórí ìjọba AbdulRazaq - Shagaya fọwọ́ sọ̀yà - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, August 30, 2021

Ọkàn mi balẹ̀ lórí ìjọba AbdulRazaq - Shagaya fọwọ́ sọ̀yà


Oludije sipo ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin tẹlẹ ri, Alaaji Sheriff Shagaya ti sọ pe gbogbo ẹnu loun le fi sọ pe ọkan oun balẹ gidigidi lori iṣakoso gomina ipinle Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq.

Shagaya to jade du ipo ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin sile igbimọ aṣoju-ṣofin niluu Abuja, ẹni to jade lẹkun Ilorin West/Asa Federal Constituency nigba kan ri lo sọrọ naa lopin ọsẹ to kọja yii.

Nibẹ lo ti gbe oṣuba kare fun gomina AbdulRazaq fun awọn akanṣe iṣẹ manigbagbe to ti ṣe laaarin ọdun meji.

O ni ẹgbẹ kan tawọn ṣẹṣẹ fi lọlẹ, iyẹn Sheriff Shagaya Movement (SSM), wa lati le gbe awọn aṣiwaju to ṣee fọkan tan wọle sipo to ba yẹ.

Lara awọn to wa nibẹ ni Amofin Kunle Sulyman; Alaaji Mustapha Kobe; Alaaji Baba Olosasa; Alaaji Baba Adefalu; Alaaji Razaq Gidado; Ọnọrebu Hameed Ọladipupọ; ati Alaaja Kubura Kasum. 

Awọn miran ni Alaaji Kabir Shagaya, Alaaji Hakeem Shagaya; Alaaji Mukhtar Shagaya; Ọnọrebu Suleiman Sai Kayi; Alaaji Majeed Temidire, atawọn mi in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI