Ọpẹ o! Ori ko Ọba Ara, gbaujmọ olorin yọ lọwọ iku ojiji - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, August 22, 2021

Ọpẹ o! Ori ko Ọba Ara, gbaujmọ olorin yọ lọwọ iku ojiji


Titi di asiko ti a fi ṣakojọpọ iroyin yii tan, lawọn ololufẹ gbajugbaja olorin Kristẹni nni, Ọmọwe Rotimi Onimọlẹ tọpọ awọn eeyan mọ si Ọba Ara ṣi n ba a yọ, ti wọn n ba a dupẹ lọwọ Ọlọrun.
 
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee to kọja yii la gbọ pe Ọba Ara kagbako ijamba ọkọ, nibi ti mọto rẹ ti gbokiti wọnu igbo lori ere.
 
AWIKONKO gbọ pe ọkan lara awọn mọto ti wọn n lọ lopopona lo gba mọto Ọba Ara lori ere, ti mọto naa si gbokiti lọpọ igba wọnu igbo, ṣugbọn ti ori pada ko o yọ lọwọ iku.
 
Ọba Ara atawọn meji kan la gbọ pe wọn wa ninu mọto rẹ lọjọ naa, ti ko si sẹni to ku ninu wọn, bo tilẹ jẹ pe wọn farapa.
 
Awọn oṣiṣẹ ẹṣọ oju popona tijọba apapọ la gbọ pe wọn sare debẹ lati gbe gbogbo wọn lọ si ọsibitu fun itọju to peye, ti wọn si tun ko awọn mọto naa lọ teṣan ọlọpaa.
 
Nigba to n sọrọ, Ọba Ara sọ pe "Ẹ ṣaa maa ba mi dupẹ. Ọlọrun ṣẹṣẹ ko wa yọ lọwọ iku ojiji ni. A kagbako ijamba ọkọ laipẹ yii. Ẹ ba mi dupẹ."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI