Nítorí ẹ̀sun jìbìtì: Wọ́n ju Fáfúnmi, ọmọ Nàìjíríà sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́rin àti oṣù mẹ́ta l'Amẹ́ríkà - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Sunday, August 22, 2021

Nítorí ẹ̀sun jìbìtì: Wọ́n ju Fáfúnmi, ọmọ Nàìjíríà sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́rin àti oṣù mẹ́ta l'Amẹ́ríkà


Ọdun mẹrin ati oṣu mẹta gbako ni Ismaila Fafunmi, ọmọ orilẹ-ede Naijiria yoo lo lọgba ẹwon ilẹ Amẹrika lori ẹsun jibiti ti wọn fi kan an.
 
Adajọ ile-ẹjọ naa, Karen Caldwell, sọ pe ki Fafunmi lọ lo oṣu mọkanlelaadọta gbako lẹwọn lati le fi kẹkọọ wi pe iwa jibiti ko dara fun ọmọluabi.
 
Wọn ni ayederu ifẹ ori ayelujara ni Fafunmi fi n lu awọn eeyan ni jibiti, ati pe awọn arugbo lo maa n tan jẹ wi pe oun yoo fẹ wọn. Lẹyin tawọn yẹn ba si gba fun un tan, ṣe ni yoo gba gbogbo owo ọwọ wọn, ko to salọ.

A gbọ pe lẹyin ti wọn ba fi Fafunmi silẹ tan, yoo tun wa labẹ iṣakoso ilẹ Amẹrika fun ọdun mẹta gbako, ti wọn yoo maa ṣọ awọn iwa ati iṣesi ẹ kaakiri.
 
Ilu Indianapolis la gbọ pe Fafunmi n gbe l'Amẹrika, gẹgẹ bi awón iwe ti wọn ri gba lọwọ ẹ ṣe ṣalaye.

Inu oṣu kẹfa ọdun 2018 ni wọn ti bẹrẹ ẹjọ naa pẹlu Fafunmi.
 
Wọn loun pẹlu awọn ọrẹ rẹ yoo lọ ṣi ayederu fesibuuku lai maa fi lu awọn eeyan ni jibiti nilẹ Amérika ko to di pe aṣiri rẹ pada tu sita.
 
Oṣu kẹjọ, ọdun to kọja la gbọ pe Fafunmi ṣẹṣẹ gba pe oun jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan oun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI