Ori ko Tọheeb yọ lọwọ iku ojiji nibi to ti fẹẹ lọ jale n'Ilọrin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, August 7, 2021

Ori ko Tọheeb yọ lọwọ iku ojiji nibi to ti fẹẹ lọ jale n'Ilọrin


Kani ki i ṣe ọpẹlọpẹ awọn ẹlẹyinju aanu ti wọn tete gba gendekunrin ti ẹ n wo yii silẹ ni, boya ki ba ti gbagbe wi pe oun wa sile aye ri.
 
AWIKONKO gbọ pe gendekunrin naa, Aina Tọheeb ko niṣẹ meji ju ko maa jale lawọn ile onile lọ, koda ti wọn sọ pe ṣe ni yoo fo fẹnsi wọnu ọgba ile to ba ti fẹẹ jale, ti yoo si ja ilẹkun wọle.

Nigba ti aṣiri rẹ maa tu, ana, ọjọ Ẹti, Furaidee la gbọ pe Tọheeb lọ si ile kan to wa lagbegbe Danialu Upper Gaa-Akanbi area in Ilorin, Kwara state.
 
Bo ṣe fo fẹnsi wọnu ọgba ile yii ni wọn lawọn araale ti kofiri rẹ, ti won si pariwo sita.

Ko to di pe Tọheeb loun maa fo fẹnsi naa pada sita lati salọ, awọn ti bo o, ti wọn si dana iya fun un.

Awọn ti wọn kaanu ẹ ni wọn gba a silẹ, ti wọn si lọ fa a le awọn ọlọpaa lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI