Lẹyin tọwọ tẹ ẹ, Kọla to n fipa bawọn ọmọ kekeeke laṣepọ n'Ilọrin bu sẹkun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, August 7, 2021

Lẹyin tọwọ tẹ ẹ, Kọla to n fipa bawọn ọmọ kekeeke laṣepọ n'Ilọrin bu sẹkun


Ọrọ buruku toun tẹrin lọjọ Ẹti, Furaidee ana, nigba ti awọn oṣiṣẹ eleto aabo Sifu Difẹnsi nipinlẹ Kwara foju baale ile ẹni ọdun marundinlogoji kan, Kọla Mọgaji han fawọn akọroyin niluu Ilọrin, to si jẹ pe ṣe lo bu sẹkun.

AWIKONKO gbọ pe Kọla to fẹran lati maa bawọn ọmọ kekeeke tọjọ ori won ko ti i to nnkan laṣepọ kaakiri igboro ilu Ilọrin lọwọ palaba re segi lẹyin to fipa ba ọmọdebinrin, ọmọ ọdun mẹrinla kan lopọ.
 
Agbegbe Ọja Ago, to wa niluu Ilọrin ni Kọla sọ pe oun n gbe, to si ni iṣẹ awọn to n ran aṣọ loun yan laayo.
 
Siwaju si i la gbọ pe Kọla ṣi n jẹjọ lọwọ lori ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan an nile-ẹjọ, ti ẹjọ naa ko si ti i pari, ko to tun ṣe mi in.
 
Babawale Zaid Afọlabi, alukoro ileeṣẹ Sifu Difẹnsi nigba to n sọrọ sọ pe ọmọ ọdun mẹta lo ti kọkọ ba laṣepọ, eyi ti wọn fi gbe e lọ sile-ẹjọ loṣu meloo kan sẹyin.
 
O niwadii naa lawọn ṣi n ṣe lọwọ, ti ko si ti i pari, ki iroyin to tun tẹ awọn lọwọ wi pe ọkunrin naa tun ti lọ fipa ba ọmọdebinrin miran laṣepọ.
 
Bẹẹ lo sọ pe afi kawọn tun pada foju ẹ ba ile-ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI