Oríire nlá! Àwọn aráàlú tún jẹ́ anfààní Kẹ̀kẹ́ Márúwá ọgọ́rùn-ún ní Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Tuesday, August 31, 2021

Oríire nlá! Àwọn aráàlú tún jẹ́ anfààní Kẹ̀kẹ́ Márúwá ọgọ́rùn-ún ní Kwara


Titi di asiko taa ṣakojọpọ iroyin yii tan, bi wọn ba gun ẹṣin ninu awọn olugbe ipinlẹ Kwara, wọn ko nii kọsẹ rara, pẹlu bi awọn eeyan ṣe n gbadura fun ijọba ipinlẹ naa labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq.
 
Ọjọ Aje, Mọnde, ana nijọba ipinlẹ naa fi ẹbun Kẹkẹ Maruwa ọgọrun-un ta awọn olugbe ipinlẹ naa lọrẹ, pẹlu erongba lati tubọ jẹ ki igbokegbodo ọkọ kẹsẹjari, ki iṣẹ ati oṣi si le dohun igbagbe.
 
Ẹgbẹ kan ti wọn pe ni Tricycle Owners Association of Nigeria (TOAN) la gbọ pe wọn ijọba ipinlẹ naa ba dowo pọ lati gba Kẹkẹ Maruwa yii.
 
Banki eleto ẹyawo kan ti wọn pe ni SEAP Microfinance Institute, la gbọ pe wọn gbe ẹyawo naa kalẹ fun ijọba, lojuna lati le jẹ kawọn araalu jẹ mudunmudun eto oṣelu awaarawa.
 
Nibẹ ni Gomina AbdulRazaq ti gbe oṣuba kare fun SEAP Microfinance Institute, SIMBA/TVS, ati TOAN fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe lati le jẹ ki eto naa wa si imuṣẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI