Ọpẹ́ o! JAMB wọ́gilé máàkì láti wọlé sílé ẹ̀kọ́ gíga - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, August 31, 2021

Ọpẹ́ o! JAMB wọ́gilé máàkì láti wọlé sílé ẹ̀kọ́ gíga


Ajọ to n ṣagbatẹru idanwo lati wọle sile ẹkọ giga, iyẹn Joint Admissions and Matriculation Board (JAMB) ti kede sita wi pe awọn ko ni maa lo maaki, iyẹn Cut-Off Mark mọ fawọn akẹkọọ to ba fẹẹ wọle sile ẹkọ giga, bẹrẹ lati akooko yii lọ.
 
JAMB sọ pe o ku sawọn ile-ẹkọ giga lọwọ lati mọ awọn ọna tabi ilana ti wọn yoo maa fi gba awọn akẹkọọ tuntun wọle sile-ẹkọ wọn.
 
Oni, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ni ajọ JAMB kede iroyin yii sita nibi ipade ti wọn ṣe lori ilana eto igbaniwọle sile-ẹkọ, iyẹn Policy Meeting tọdun 2021.

Ipade naa ti minisita fọrọ eto ẹkọ lorilẹ-ede yii, Malamu Adamu Adamu lewaju rẹ ni wọn ti fẹnuko lori awọn igbesẹ ati ilana tuntun kọọkan.
 
Nigba to n sọrọ, alaga ajọ JAMB, Ọjọgbọn Is-haq Oloyede, sọ pe awọn fasiti kan bii tilu Maiduguri sọ pe aadọjọ {150} ni maaki tawọn fẹẹ lo; fasiti Usman Dan Fodio tilu Ṣokoto sọ pe ogoje {140} ni maaki tawọn fẹẹ lo; fasiti Pan Atlantic lawọn fẹẹ lo maaki igba-le ni mẹwaa {210}; fasiti Eko fẹẹ lo igba {200} maaki; LASU fẹẹ lo 190.
 
Oloyede sọ pe niwọn igba ti ẹnu gbogbo awọn fasiti wọnyi ko ti ko lori maaki kan, yoo dara pupọ bawọn ba le yọwọ kuro lori ọrọ eto igbaniwọle sawọn ile-ẹkọ giga. 
 
Bẹẹ ni wọn sọ pe bo tilẹ jẹ pe awọn ko lo maaki, ati pe awọn ile-ẹkọ giga ni wọn yoo mọ ọna ti wọn fẹẹ fi gba awọn akẹkọọ wọn, sibẹ, wọn lawọn ni yoo ṣagbatẹru eto igbaniwọle naa, ti wọn si gbọdọ fi idanimọ gbogbo akẹkọọ wọn patapata ranṣẹ si wọn lati ori ikanni ayelujara wọn, iyẹn JAMB CAPS.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI