Oṣelu ki i ṣe boo ba o pa, boo ba o bu lẹsẹ - APC ṣalaye f'Oyedepo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, August 20, 2021

Oṣelu ki i ṣe boo ba o pa, boo ba o bu lẹsẹ - APC ṣalaye f'Oyedepo


Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress nipinlẹ Kwara ti sọ fun Akọgun Oyedepo lati tẹri igberaga rẹ ba, ati pe ko dẹkun oṣelu ẹtanu, nitori pe ọrọ oṣelu ki i ṣe ki wọn maa leri iku si ara wọn.
 
Wọn ni oṣelu ti awọn eeyan n ṣe lorilẹ-ede yii, bi ẹni to n gba ere idije ati ifigagbaga lasan ni, ki i ṣe nipa rironu iku sira wọn.
 
Alaaji Tajudeen Aro Fọlaranmi, ẹni to jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ naa lo sọrọ yii jade wi pe ki Oyedepo tun ero rẹ pa lori ọna to n gbe ọrọ oṣelu rẹ gba lakooko yii.
 
O ni ọrẹ lo yẹ ki wọn maa ba ara wọn ṣe, ki i ṣe nipa ija, ati pe bi o ba ri oun ti ko tẹ ẹ lọrun, dibo ko maa leri, awọn atunṣe to ba yẹ lo yẹ ko maa wa.
 
Siwaju si i ni ẹgbẹ oṣelu APC tun sọ pe ko si awọn nnkan ti wọn le fi ka Oyedepo si alẹnulọrọ tabi aṣiwaju ọrọ oṣelu nipinlẹ Kwara, ti wọn le fi pe e sibi ipade alaafia pẹlu Gomina Abdulrahman Abdulrazaq.
 
Ọrọ yii ko dee de jade, bi ko ṣe ti awọn ọrọ ti wọn ni ọkunrin naa bawọn akọroyin sọ laipẹ yii, nibi to ti n yẹyẹ ijọba ipinlẹ naa, to si tun n sọrọ buruku sawọn alẹnulọrọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI