Adanu nla niku Ọmọwe Ayọtunde jẹ ni fasiti Kwara - Gomina - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, August 16, 2021

Adanu nla niku Ọmọwe Ayọtunde jẹ ni fasiti Kwara - Gomina


Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti sọ pe adanu nla niku gbajugbaja ọmọwe nni, Ọmọwe Ayótunde Alao ti fasiti ipinlẹ naa jẹ fun gbogbo awọn eeyan.
 
AbdulRazaq sọ pe asiko tawọn eeyan nilo rẹ julọ, paapaa julọ lori ọrọ eto ẹkọ fasiti naa lo jade laye lai ro tẹlẹ.
 
Ninu atẹjade ibanikẹdun ti Gomina AbdulRazaq gbe jade lati ọwọ akọwe iroyin rẹ, Ọgbẹni Rafiu Ajakaye lo ti sọ pe awọn ko le gbagbe ipa to ko nigba aye rẹ, lori idagbasoke fasiti naa.

O ni olukọ to yọranti, to si jẹ ọmọ ipinlẹ naa to ṣee mu yangan.
 
O bawọn alakoso fasiti, awọn akẹkọọ, paapaa idile oloogbe naa kẹdun, to si gbadura pe ki Ọlọrun tẹ ẹ si afẹfẹ rere.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI