Wòlíì Ayọ̀délé ró àwọn ará ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ lágbára lọ́nà tí wọ́n yàn láàyò - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, August 24, 2021

Wòlíì Ayọ̀délé ró àwọn ará ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ lágbára lọ́nà tí wọ́n yàn láàyò


Ṣẹnkẹn bayii ni inu awọn ọmọ ijọ INRI Evangelical Spiritual Church, ti Primate Elijah Ayọdele jẹ oludasilẹ rẹ l'Ekoo n dun, pẹlu bi wọn ṣe jẹ anfaani irolagbara ọtun.

Kẹkẹ Maruwa, at'awọn nnkan miran lawọn ọmọ ijọ naa gba lati maa fi pawo wọle sapo ara wọn.

Ọjọ Aiku, Sannde ijẹta yii nibi ayẹyẹ isin ọjọ isinmi lawọn ọmọ ijọ naa ti ri oore ọfẹ gba lọwọ olori ijọ wọn.

AWIKONKO gbọ pe ọkan lara awọn ọmọ ijọ naa to yan iṣẹ irun ṣiṣe laayo, ṣugbọn ti ko ni owo lati fi ra irinṣẹ irun ni Wolii Ayọdele fun ni irinṣẹ, to si tun gbe Kẹkẹ Maruwa fun ọkunrin kan toun naa n ṣiṣẹ maruwa.
 
Wọn lawọn eeyan yii ko ronu nipa rẹ wi pe awọn yoo ri aanu nla bayii gba ninu ijọ naa, ati pe idunnu nla lo jẹ fun wọn.
 
Fọnran bi eto naa ṣe lọ ree.
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI