Yoruba ki i ṣe ẹya kan naa, a kan n pe ara wa ni Ọmọ Oduduwa ni - Ọmọwe Fajẹnyọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, August 4, 2021

Yoruba ki i ṣe ẹya kan naa, a kan n pe ara wa ni Ọmọ Oduduwa ni - Ọmọwe Fajẹnyọ


Aarẹ gbẹ awọn olukọ ede Yoruba kaakiri ile ẹkọ tawọn olukọni lorilẹede Naijiria ni Ọmọwe Sọji Aderẹmi Fajẹnyọ. Ẹka ikẹkọọ ede Yoruba ni wọn wa ni ile ẹkọ awọn olukọni, iyẹn Federal College of Education to wa nilu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun. Ọmọwe Fajẹnyọ tun jẹ Olu Ọmọ ilu Agbọṣaga nilu Ila Ọrangun, ipinlẹ Ọṣun. 
 
Bakan naa ni wọn tun jẹ onkọtan ati onkọwe to ti kọ iwe loriṣiriṣi. Laipẹ yii ni wọn gba ikọ AWIKONKO lalejo, nibi ti wọn ti sọrọ nipa idaduro ilẹ Yoruba. Ẹ ka ohun ti Ọmọwe Fajẹnyọ ba Yetunde Ṣoyọye ati Bọsun Ọlaniyi sọ.
 
Ki ni ojuwoye yin nipa idaduro ọmọ Yoruba?
Yoruba bọ, wọn ni ‘bi ọmọ ko ba ba itan, yoo ba arọba’, arọba si ni wọn n pe ni baba itan. Mo ti de ile aye naa, ilẹ ta si, o ti ṣe diẹ. Yatọ si eyi, mo jẹ akẹkọọ imọ itan ati akẹkọọ ede Yoruba, ko to di pe mo wa a di olukọ itan ati ede Yoruba. Bi a ba ni ka wo o, orilẹede Naijiria ki i ṣe orilẹede kan ṣoṣo lati ibẹrẹpẹpẹ, ọtọọtọ ni onikaluku ti wa. Lọdun 1914 ni wọn so wa papọ, eyi ti wọn pe ni 1914 Almagamation. Lord Lugard to jẹ gomina ariwa nigba naa lo so wa papọ, ti Flora Shaw to jẹ iyawo si sọ wa lorukọ Naijiria.
 
Siwaju si i, Yoruba ti a n pe ara wa yii gan an, a ki i ṣe ẹya kan naa rara, a kan n pe ara wa ni ọmọ Oduduwa ni, tori pe ọdun 1917 ni Lord Lugard pe ipade awọn lọbalọba nilu Ibadan, to si ni ki gbogbo ọmọ Oduduwa bẹrẹ si i pe ara wọn ni Yoruba. Awọn kan n pe ara wọn ni ‘Lukumi’ ti wọn yọ lati ara ‘Oluku mi’; awọn kan n pe ara wọn ni ‘Anago’; awọn kan n pe ara wọn ni ‘Ọmọ Kaarọ-o-jiire’; awọn kan n pe ara wọn ni ‘Ọmọ Oduduwa’; awọn kan tiẹ wa to jẹ pe wọn ko ka ara wọn kun Ọmọ Oduduwa.
 
Olu tilu Igbo, ‘Ọmọ Ọbatala’ lo n pe ara rẹ. Bi a ba si wo o l’aye atijọ, ẹya kọọkan lo n pe ara rẹ ni ẹya tiẹ. Ẹgba wa, Igbomina wa, Ijẹbu wa, Ọyọ wa. Awọn Ọyọ gan an ni wọn n pe ni Yoruba l’aye atijọ, awọn Hausa lo si n pe wọn ni Yoruba. Ọdun 1917 ni a ṣẹṣẹ bẹrẹ si i pe ara wa ni Yoruba. Ẹya to wa ni orilẹede yii le ni irinwo (400), bo tilẹ jẹ pe ẹya mẹrin pere lo gbooro ti a mọ, awọn naa ni Yoruba, Igbo, Hausa ati Fulani. A ni awọn mi in bi Ẹdo, Itshekiri, Tifi ati bẹẹbẹẹlọ.
 
Ẹlẹyamẹya ni wa lorilẹede yii, ṣugbọn nigba ti wọn ti so wa papọ yẹn, awọn olori wa jokoo papọ, wọn si panupọ pe ka gba ominira, bo tilẹ jẹ pe awa Guusu la mura si i gidi, awọn Ariwa ko tete mura si i, tori pe awọn ni wọn jẹ igi wọrọkọ to n da ina ru, eyi to fa afasẹyin, to jẹ pe ọdun 1960 la to o ṣẹṣẹ gba ominira naa. Ọdun 1958 si 1959 ni awọn bi i Oloogbe Ọbafẹmi Awolọwọ ti n gbiyanju pe ka gba ominira naa.
 
Ohun to wa n fa bawọn eeyan ṣe n pariwo pe awọn fẹẹ da duro ni pe ofin orilẹede yii to sọ pe ohun gbogbo gbọdọ lọ lai fi ti ẹlẹyamẹya ṣe, iyẹn ti wọn sọ pe ko gbọdọ si ojuṣaaju lawọn to jẹ alaṣẹ wa ko tẹle.
 
Ti ẹ ba wo ọga agba awọn agbofinro lorilẹede yii, awọn ọgalọga ninu iṣẹ ologun, gbogbo awọn ọga ologun maraarun-un lo jẹ pe ọmọ Yoruba kan ṣoṣo, iyẹn Amọo ati Irabor toun wa lati Guusu-Guusu (South-South) nikan ni wọn wa laaarin wọn, awọn mẹta yooku ninu awọn ọga ologun yii lo jẹ pe apa Ariwa ni wọn ti wa, bo tilẹ jẹ pe ọkan lara wọn ṣẹṣẹ ku ni. Bi ẹ ba si wo awọn bi i ọga aṣọbode, ti Kọsitọọmu ati Imigireṣan; awọn ẹṣọ oju popona, apa Ariwa ni wọn ti wa. Bawo ni ọbọ ṣe ṣe ori ti inaki naa ko ṣe? Eleyi lo n bi awọn eeyan ninu pe bi ẹ ba sọ pe ọmọ Naijiria kan ṣoṣo ni wa, ṣe ko wa a si awọn to jẹ akọṣẹmọṣẹ ti wọn to o fiṣẹ oogun ran l’aaarin awọn ẹya yooku ni?
 
Ẹ maa ri i pe ki i ṣe Yoruba nikan ni wọn n fẹ ja ijagbara yii, bo tilẹ jẹ pe tawọn ẹya Igbo ti pẹ. Wọn ti kọkọ ja ogun Biafra laaarin ọdun 1967 si ọdun 1970 ri, ti Ojukwu dari rẹ nigba yẹn. Igba ti ogun yẹn pari ni Ọgagun Gowon ṣẹṣẹ rẹ wọn lẹkun, ṣugbọn bayii naa ni wọn tun ri i pe wọn ṣi n yan awọn jẹ, eyi lo jẹ ki oogun ti wọn le ju ti Yoruba lọ.
 
Nitori naa, ẹkọ gbibona ọrọ yii n fẹ suuru, pẹlẹ lo si gba ka fi ṣe e. A ko le fi ogun ja ominira yii. Bi Yoruba gan an ba da duro, wahala ṣi ma maa ṣẹlẹ, bi apẹẹrẹ, ni ipinlẹ Ogun, awọn ẹya Yewa ṣi n fi ẹhonu han wi pe awọn ko ti i jẹ gomina latigba ti wọn ti da ipinlẹ naa silẹ, ati pe wọn n yan awọn jẹ. Nitori naa, ko gbọdọ si ojuṣaaju. Nnkan akọkọ ti a gbọdọ kọkọ mu kuro ninu ọrọ wa ni ojuṣaaju, ki a si tẹle ofin ‘pin-in-re, la-a-re’, eyi t’awọn oloyinbo n pe ni Federal Character, eyi to ti wa ninu ofin orilẹede yii tipẹ.
 
Bi a ba tiẹ maa da duro, nnkan akọkọ to yẹ ko kọkọ waye ni pe a gbọdọ ṣe atunto orilẹede yii, gẹgẹ bi Ọmọwe Ṣọla Adeọṣun ṣe maa n sọ wi pe ki i ṣe atunto nikan ni ka ṣe, a ni lati di ‘atunbi’ pẹlu. Awa funra wa gbọdọ di atunbi, ka ma si ṣe ojuṣaaju ara wa yatọ si atunto ti a n pariwo, iyẹn ni pe ka gbe iwa ọmọluabi wọ bi ẹwu, ka jẹ olotitọ, ka ma si ṣe ojuṣaaju, ki iwa jẹgudujẹra kuro lọkan wa, gbogbo awọn nnkan wọnyii ṣe pataki pupọ.
 
Ki i ṣe orilẹede Naijiria ni idaduro bayii yoo ti kọkọ waye, awọn orilẹede bi i South Korea, North Korea jọ wa papọ tẹlẹ ni, ko to di pe onikaluku wọn da duro lọtọọtọ, ṣugbọn o ni awọn igbesẹ ti wọn tẹle. Ọjọgbọn Banji Akintoye ti n sọ awọn igbesẹ naa fun wa, lara awọn igbesẹ yii ni wọn ti sọ pe wọn yoo kọkọ kọ lẹta ẹhonu lọ sọdọ ajọ agbaye, lẹyin eyi ni ajọsọ ati ajọro yoo waye, eyi tawọn oloyinbo n pe ni Referendom.
 
Tori bi a ba sọ pe a fẹẹ gba orilẹede Yoruba pẹlu wahala, ko ni i rọrun, tori wọn sọ pe ibẹrẹ ogun la maa n ri, a ki i mọ opin rẹ. Yoo ba oju, yoo si tun ba imu nigba ti ọrọ naa ba ṣẹlẹ. Ọpọ eeyan ni yoo ku si i, eto ọrọ aje yoo dẹnukọlẹ. Ẹ wo nnkan to ṣẹlẹ lẹyin ogun Biafra, laaarin ọdun 1971 si ọdun 1973 ni iwa ole jija di tọrọfọnkale, paapaa lawọn to wa lati Guusu-Guusu ati Guusu-Ila-Oorun. Eto ọrọ aje to dẹnukọlẹ lo jẹ ki wọn bọ sita lati maa digunjale. Ogun maa n koba eto ọrọ aje, eto oṣelu, eto amuludun ati oniruuru eto yooku ni. 
 
Njẹ eto ọrọ aje ilẹ Yoruba lagbara lati da duro pẹlu awọn ipinlẹ marun-un ti a ni, bi a ko ba ka Kwara ati Kogi, ati pe njẹ a ni awọn amuyẹ lati da duro?
Yoruba bọ, wọn ni ‘wọnti-wọnti kọ leyin, to ba ti le ge mọsa, o ti tan.’ Awọn ipinlẹ ti a ni ko ni nnkan ṣe pẹlu idaduro Yoruba. Ti ẹ ba wo o nigba aye Baba wa Ọbafẹmi Awolọwọ, a maa ri i pe Iwọ-Oorun Naijiria lo ni idagbasoke julọ ni Naijiria. Ọdun 1955 ni ẹkọ ọfẹ bẹrẹ, agbara ṣi wa daadaa to jẹ pe wọn ko woju ijọba apapọ, wọn ṣi n fun wọn ni agbara lati da duro, ijọba apapọ ko tiẹ fi bẹẹ lagbara to ẹkun nigba yẹn, ti idagbasoke nla-nla si n waye. Koko (Cocoa) nikan la fi n ṣeto ọrọ aje nigba naa. Owo Koko ni won fi kọ ile gogoro s’Ibadan, wọn tun kọ papa iṣere Liberty, tẹlifiṣan akọkọ nilẹ Afrika, WNTV, owo Koko ni wọn fi ṣe e.
 
Fun idi eyi, a lawọn nnkan alumọọni ti a le fi da duro ju awọn ẹya yooku lọ. Yatọ si ẹpa, ki ni awọn Ariwa tun ni, eyi si ni wọn fi n bẹru pe bawo lawọn ṣe fẹẹ ṣe e bi iyapa ba de. A ni awọn ti wọn to o fiṣẹ ogun ran nilẹ Yoruba, nipa ẹkọ iwe ni, imọ ẹrọ, ti a ba sọ ti oṣelu, aabo, iwosan, eto ọrọ aje, Yoruba mọ nipa ẹ gidi. To ba jẹ pe ijọba n ṣe daadaa ni, ẹ maa ri i pe Yoruba lo n mu oke julọ ni gbogbo ọna. Ẹyin patapata lawọn ti wọn wa loke ọya wa nipa imọ ẹkọ. Aipọ wa ko ni ka ma le da duro, koda, ilọsiwaju gan yoo ba wa ju bi a ṣe wa yii lọ.
 
Yoruba ni awọn amuyẹ nipa alumọọni ilẹ, yatọ si Koko ti a gbojule laye atijọ. Ipinlẹ Ogun naa ni alumọọni ilẹ ti wọn fi n ṣe simẹnti, a ni awọn ibi ti wọn ti le wa goolu ati irin ni Ileṣa.
 
Oloogbe Ọjọgbọn T.M Ilesanmi kọ iwe kan nipa Iṣẹ Iṣẹmbaye nilẹ Yoruba. Iwe yẹn kun debi pe gbogbo ibi ti alumọọni ilẹ wa nilẹ Yoruba lo wa nibẹ. Yoruba lawọn nnkan alumọọni daadaa, to jẹ pe a maa ṣiju si wọn nigba ti a ba da duro. Epo Rọbii tun wa nipinlẹ Ondo ati Ogun. Ọkẹ aimọye lawọn to le ṣe akoso eto ọrọ aje wa. Yoruba kawe gidi, ṣugbọn iṣoro wa ni iwa jẹgudujẹra ati ojuṣaaju ti a ni. Bi a ba fi otitọ ṣe ijọba wa, ti a si ri awọn to ni ifẹ ilu lọkan bi Oloogbe Ọbafẹmi Awolọwọ. Awọn ti a ni lasiko yii kan n fi orukọ Awolọwọ gba irawọ ni. Bi a ba ri awọn eeyan bi Awolọwọ ni, iwaju ni Yoruba ki ba wa.
 
Njẹ ẹ ro pe ọrọ idaduro ti wọn n pariwo yii ko ni pada di ogun nla pẹlu bi nnkan ṣe n lọ wẹrẹwẹrẹ yii?
Bi a ba le ewurẹ titi, to ba yiju pada, wahala ni. Akọkọ ni pe a gbọdọ tọ ọna to tọ lati le ja ija ominira. Nigba ti a maa gba ominira Naijiria nigba naa, pẹlẹkutu la fi gba a, tori pe wọn tẹle ilana ofin. A si ri awọn orilẹede mi in to jẹ pe pẹlu ogun lawọn fi gba a, ṣugbọn ogun ki i bimọ rere. A gbọdọ tẹle ọna to tọ ka to o sọ pe a fẹẹ da duro fun ominira. A gbọdọ fi ẹhonu wa han si ajọ agbaye pẹlu awọn ẹri to daju, lati jẹ ki wọn mọ pe iya n jẹ wa, ki wọn si sọ awọn igbesẹ ti a maa gbe. Wọn gbọdọ fi to awọn lọbalọba leti lati jiroro. A ko gbọdọ gba adura ogun lati fi gba ominira lọwọ awọn amunisin, tori pe imunisin ẹlẹẹkeji la wa yii, ti awọn oloyinbo si n pe ni neocolonialism.
 
Bawo lo ṣe fẹẹ rọrun lati tẹle ilana ofin idaduro nigba tawọn bi i gomina, awọn ọba alaye atawọn agbaagba Yoruba kọọkan ko ṣetan lati pin?
Ọna ti Oloye Sunday Adeyẹmọ Igboho n gba lati fẹ ki Yoruba da duro lawọn agbaagba ko faramọ. Ko sẹni to n fẹ ki ogun ṣẹlẹ, tori pe oju ti la kọja tatijọ. A ko gbọdọ lo ilana ogun lati ja ominira. Bi ọmọde ba ṣubu, yoo wo iwaju, bi agba ba ṣubu, ẹyin lo maa wo. Bakan naa bi ọmọde ba n ge igi nigbo, agba lo mọ ibi to maa wo si. Idi ree ti a fi gbọdọ tẹle ohun tawọn agba ba sọ. Ko si agba Yoruba to faramọ bi wọn ṣe n yan wa jẹ, ṣugbọn Yoruba naa lo sọ pe ọbẹ n mi nikun agba. Bi agba ba n sọ ọ labẹlẹ pe ka pin, wọn ko ni le jade sọ ọ sita wi pe ka pin, tori pe wọn ti mọ atubọtan ogun.
 
Bi a ba pin naa, ṣe ko ni i si iyanjẹ ni? Bi a ba n sọ nipa awọn ọmọ Yoruba to ti di ipo mu ju lorilẹede yii, ẹ maa ṣakiyesi wi pe ipinlẹ Ogun ni wọn ti wa, iyẹn bi a ba n sọ nipa ipo Aarẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ni; lẹka eto idajọ, ọmọ ipinlẹ Ogun ni; Gomina ile ifowopamọ nigba kan ri, Ọlatunde Vincent, ọmọ ipinlẹ Ogun ni, atawọn mi in bẹẹ, koda, igbakeji Aarẹ wa lọwọlọwọ, Yẹmi Ọṣinbajo, ọmọ ipinlẹ Ogun ni. Ẹlẹyamẹya yoo ṣi waye bi a ba pin, ayafi bi a ba ni iwa ọmọluabi, ka si ni ifẹ ara wa ati ọtitọ inu.
 
Ki ni amọran yin, paapaa fawọn ọmọ Yoruba nipa rogbodiyan to n lọ lọwọ yii?
Mo ti sọ ṣaaju, a ni lati gbe iwa ọmọluabi wọ bi ẹwu. Ninu idanilẹkọọ ti igbimọ awọn agba Yoruba ṣe laipẹ yii ni wọn ti jẹ ka mọ pe Yoruba ti a n pe ara wa ko nitumọ kankan, wi pe bi ẹni tabuku wa lawọn Ariwa ti wọn pe wa ni Yoruba, ati pe ki lo de ti a ko pe ara wa ni orilẹede Ọmọluabi dipo Yoruba. A ni lati tẹpa mọṣẹ, ka jẹ olotitọ, ka yago fun ojuṣaaju, ka nifẹẹ ati aanu ara wa, bi a ba le gbe awọn abuda yii wọ bi ẹwu, a ko ni le kabamọ lọjọ iwaju wi pe a gba orilẹede gẹgẹ bi ọmọ Yoruba.
 
Ki Ijẹbu ri ara rẹ gẹgẹ bi ọmọ Yoruba, ki Ifẹ ri ara rẹ gẹgẹ bi ọmọ Yoruba, ki Igbomina ri ara rẹ gẹgẹ bi ọmọ Yoruba, ki Ẹgba ri ara rẹ gẹgẹ bi ọmọ Yoruba, ki Ekiti ri ara rẹ gẹgẹ bi ọmọ Yoruba, ka si ri ara wa gẹgẹ bi ọkan ṣoṣo.
 
Lafikun, orukọ wo lẹ wo o pe a ko ba maa jẹ yatọ si Yoruba?
Mo ti sọ ṣaaju wi pe Yoruba ki i ṣe ẹya kan naa. Oriṣiriṣi ọrọ atẹnudẹnu lo si waye nipa orukọ Yoruba. Awọn kan sọ pe o wa ninu iwe Ezra wi pe ẹya Heberu ni wa, wi pe Yoarib ni wọn sọ di Yoruba; awọn kan sọ pe awọn Ariwa lo pe wa bẹẹ lati fi ṣapejuwe agabagebe inu wa. Ọmọwe Alaran Lọdun 2007 sọ pe ‘Yoo rubọ’ ni wọn sọ di Yoruba. Fun idi eyi, ẹnu gan an ko ti i ko lori itumọ Yoruba. Mo si sọ ṣaaju pe awọn Ọyọ ni wọn n pe ni Yoruba tẹlẹ. Ijẹbu gan an ko gba pe Yoruba lawọn. 
 
Awọn apa kan nilu Akurẹ; Olu Igbo nipinlẹ Ondo sọ pe ọmọ Ọbatala lawọn. Awọn kan ni Akurẹ ko gbagbọ pe Ifẹ ni orirun agbaye tabi Yoruba. Ariyanjiyan ṣi maa waye lori orukọ Yoruba Nation, boya bi a ba kuku pe ara wa ni ọmọ Oduduwa, ṣugbọn nigba ti igbọnsẹ ba de oju ṣuṣu, wọn ni furọ maa la. Awọn agba si sọ pe ka de eti odo ka to o fona. Nigba ti a ba de oju agbami, awọn agba yoo fun wa lorukọ ti a ma maa jẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI