Lẹyin ọjọ mejilelọgbọn, awọn ọmọ ẹyin Sunday Igboho gbominira lọwọ DSS - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, August 4, 2021

Lẹyin ọjọ mejilelọgbọn, awọn ọmọ ẹyin Sunday Igboho gbominira lọwọ DSS


Ile-ẹjọ giga tiluu Abuja lonii ti paṣẹ pe anfaani wa fun gbogbo awọn mejila ti wọn ko nile Oloye Sunday Adeyẹmọ, iyẹn Sunday Igboho lọjọ kinni, oṣu keje lati gba beeli ara wọn.

Onidajọ Obiora Egwuatu lo gbe idajọ naa kalẹ lonii, Ọjọru, Wẹside.

Agbẹjọro Igboho, Pẹlumi Ọlajẹngbesi lo pe ẹjọ naa, nibi to ti n bẹ ile-ẹjọ wi pe ko fun awọn mejila tawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ko nile Sunday Igboho lanfaani beeli.

Ọjọ kinni, oṣu keje ni awọn oṣiṣẹ ọtẹlẹmuyẹ lati ilu Abuja yawo ile Sunday Igboho to wa ni Ṣoka niluu Ibadan, nibi ti wọn ti pa eeyan meji ọtọọtọ.
Bo tilẹ jẹ pe ṣaaju asiko yii ni ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ti sọ pe bi ile-ẹjọ ba fun awọn eeyan naa lanfaani beeli, o daju wi pe wọn yoo salọ, ṣugbọn ti ile-ẹjọ sọ pe awawi lasan ni.
 
Onidajọ Egwuatu sọ pe gbogbo awọn mejila naa ni wọn lẹtọọ si afaani beeli labẹ ofin orilẹ-ede yii, nitori pe wọn ti pẹ ju bo ṣe yẹ lọ lahamọ.
 
Ahamọ awọn DSS yii la gbọ pe awọn eeyan naa yoo ṣi wa titi digba ti wọn yoo fi mu awọn amuyẹ to rọ mọ beeli wọn naa ṣẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI