Àyẹ̀wò ọ̀fẹ́ bẹ̀rẹ̀ lórí àwọn Kẹ̀kẹ́ Márúwá tíjọba Kwara pín fáwọn aráàlú - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, September 15, 2021

Àyẹ̀wò ọ̀fẹ́ bẹ̀rẹ̀ lórí àwọn Kẹ̀kẹ́ Márúwá tíjọba Kwara pín fáwọn aráàlú


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti bẹrẹ ayẹwo ọfẹ fun gbogbo awọn ọgọrun-un Kẹkẹ Maruwa ti wọn pin fawọn araalu laipẹ yii.
 
Kwara pẹlu ajọṣepọ ileeṣẹ SIMBA TVS la gbọ pe wọn pawọpọ lati ṣagbatẹru ayẹwo ọfẹ naa, eyi to bẹrẹ lakọtun lonii, Ọjọru, Wẹside.

Ileeṣẹ SIMBA TVS lo ṣe awọn Kẹkẹ Maruwa tijọba Kwara pin fawọn araalu naa. Lojuna lati ma jẹ ki kudiẹ-kudiẹ wa lo mu ki wọn fẹẹ ṣe ayẹwo ọfẹ naa lati mọ ipo ti awọn ẹnjiini Maruwa kọọkan wa, ko to di pe o bẹrẹ iṣẹ.
 
Oludamọran pataki fun gomina lori ọrọ to nii ṣe pẹlu agbegbe {Community Intervention}, Kayọde Oyin-Zubair lo fidi ọrọ yii mulẹ, to si ni gbogbo ileri ti ijọba ṣe lo ti ṣiṣẹ le lori fun gbadun awọn araalu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI