Ẹ fura o! Wọ́n fẹ̀sùn ìjínigbé kan Buhari, aláàbọ ara, odindi ìdílé kan ló fẹ́ẹ́ jígbé - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, September 21, 2021

Ẹ fura o! Wọ́n fẹ̀sùn ìjínigbé kan Buhari, aláàbọ ara, odindi ìdílé kan ló fẹ́ẹ́ jígbé


Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Katsina ti tẹ gendekunrin ọmọ ọdun mejilelogun kan, Buhari Haruna, ti wọn sọ pe ogbologbo afurasu ajinigbe ni. Ibi ti wọn lo ti fẹẹ gbowo abẹtẹlẹ ko ma baa ji idile kan gbe lọwọ palaba rẹ ti segi.
 
A gbọ pe Buhari, to n gbe nijọba ibilẹ Kankia, ipinlẹ Katsina ko le fi ẹsẹ rẹ mejeeji rin, idi ni wọn lo fi n wọ kaakiri. Bẹẹ si ni wọn sọ pe iṣẹ awọn to n tun foonu ṣe lo fi n boju, ki aṣiri rẹ ma baa tu sita.
 
Ogunjọ, oṣu kẹjọ, ọdun yii la gbọ pe Buhari tẹ atẹjiṣẹ idunkooko si ẹnikan ti wọn pe ni Hamisu Salisu, wi pe bi ko ba fẹ koun ji oun pẹlu awọn mọlẹbi rẹ gbe, ko tete san miliọnu meji naira foun.
 
Wọn ni bo ṣe n pe Salisu, lo n fi atẹjiṣẹ idunkooko naa ranṣẹ sii. Baba Salisu la gbọ pe Buhari n gbero lati jigbe tẹlẹ, ṣugbọn to pada gbọ pe ara baba naa ko ya gidi, eyi ni wọn si lo jẹ ko yi ero buruku ọkan rẹ pada.
 
Nigba ti idunkooko naa pọ, a gbọ pe Salisu gba teṣan ọlọpaa lọ lati fi to wọn leti, ti awọn ọlọpaa naa so sọ pe ko ṣe gbogbo nnkan ti Buhari ba n fẹ fun un, awọn yoo rọwọ to o.
 
Wọn lawọn ọlọpaa ti lọ duro de Buhari ninu igbo to ti fẹẹ gba owo naa lọwọ Salisu. Bo ṣe gba owo yii tan, lawọn ọlọpaa dena de e, to si bẹrẹ sii bẹbẹ pe ki wọn ṣe oun jẹjẹ.
 
Nigba to n foju rẹ han fawọn akọroyin lanaa, ọjọ Aje, Mọnde, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, SP Isah Gambo sọ pe Buhari yoo foju ba ile-ẹjọ lẹyin iwadii wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI