Wọ́n ti dájọ́ ikú fún ọlọ́pàá tó pa akẹ́kọ̀ọ́ fásitì lẹ́yin ọdún kejì - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, September 21, 2021

Wọ́n ti dájọ́ ikú fún ọlọ́pàá tó pa akẹ́kọ̀ọ́ fásitì lẹ́yin ọdún kejì


Ile-ẹjọ giga tipinlẹ Bayelsa, lopin ọsẹ to kọja yii ti da ẹjọ iku fun ọlọpaa kan ti wọn ti le danu lẹnu iṣẹ, Timade Emmanuel lori ẹsun wi pe o ṣeku pa ọmọ ọdun mọkandinlogun kan, Tarila Nikade.

Ọdun 2019 la gbọ pe Emmanuel pa Nikade, akẹkọọ fasiti tipinlẹ Nigeria, iyẹn Niger Delta University (NDU). Wọn ni maaki 4.42 CGPA lọmọkunrin naa ni ko to kagbako iku ojiji lati ọwọ Emmanuel.
 
Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Onidajọ Margaret Ayemieye sọ pe ẹsun mejeeji ọtọọtọ to nii ṣe pẹlu ipaniyan, eyi ti ọn fi kan Emmanuel lo jẹbi rẹ kọja alaye, to si ni ijiya ninu.
 
A gbọ pe ṣe ni Emmanuel yinbọn fun Nikade lọjọ naa lati gba ẹmi rẹ.
 
Latigba naa la gbọ pe awọn eeyan ti dide pe idajọ ododo gbọdọ waye, ṣugbọn ti wọn sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa gbiyanju lati ddabo bo Emmanuel, ko ma baa foju winna ofin.
 
Gbogbo igbesẹ ti wọn lawọn ọlọpaa gbe lati daṣọ aṣiri bo Emmanuel lo ja si pabo, ko to pada foju ba ile-ẹjọ lati gba idajọ iku nipa yiyẹgi fun un.
 
Igbimọ ajafẹtọ ọmọniyan lẹka eto idajọ ti Nigeria Bar Association (NBA) ti wọn gbe kalẹ la gbọ pe ẹlẹrii mẹta ọtọọtọ ni wọn gbe wa siwaju ile-ẹjọ lati jẹrii tako ọdaran naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI