Ẹ wojú àwọn afurasí adigunjalè tí wọ́n fẹ́ẹ́ fún àwọn ọlọ́pàá lówó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ l'Ékòó - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Friday, September 17, 2021

Ẹ wojú àwọn afurasí adigunjalè tí wọ́n fẹ́ẹ́ fún àwọn ọlọ́pàá lówó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ l'Ékòó


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti sọ pe awọn afurasi adigunjale ti wọn fẹẹ fawọn ọlọpaa ti aṣiri wọn tu si lọwọ yoo foju ba ile-ẹjọ laipẹ, nitori pe ṣe ni wọn tun daran-mọ-ọran.
 
Ana, Ọjọbọ, Tọside ni CPS Adekunle Ajiṣebutu to jẹ agbẹnusọ fawọn ọlọpaa sọrọ naa fawọn akọroyin, to si ni awọn mẹrẹẹrin ti wa lahamọ wọn, nibi ti wọn ti n ṣe iranwọ fun wọn.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni gbara ti ọwọ palaba awọn eeyan naa segi ni wọn ti n bẹ awọn ọlọpaa lati ṣe wọn jẹjẹ, ati pe awọn yoo fun wọn ni idaji miliọnu naira, bi wọn ba le daṣọ aṣiri bo wọn, ṣugbọn ti awọn ọlọpaa naa sọ pe ile-ẹjọ ni ki wọn lọ fun lowo naa, kii ṣe awọn agbofinro.
 
AWIKONKO gbọ pe awọn ọlọpaa to n gbogun ti iwa ọdaran lati ẹkun Area J, Ẹlẹmọrọ lo rọwọ to awọn mẹrẹẹrin ni nnkan bi aago mejila aabọ oru, lọjọ kẹrin, oṣu yii.
 
Timothy, ọmọ ọdun mẹtalelogun la gbọ pe ọwọ tẹ lagbegbe General Paint Garden, Lekki pẹlu ibọn ilewọ ati ọta ibọn loriṣiriṣi lakooko to fẹẹ lọ digun jale.
 
Bakan naa lọwọ tun tẹ Tọheed, ọmọ ọdun mejilelogun ti wọn lọmọ ẹgbẹ okunkun pọmbele ni lọwọ palaba oun naa segi lagbegbe kan naa ni nnkan bi aago kan ku iṣẹju mẹẹdogun oru.
 
Lẹyin eyi lọwọ tun pada tẹ awọn meji yooku, ti wọn lawọn yoo fun ọlọpaa ni idaji miliọnu naira, bi wọn ba le jẹ ki wọn yanju ọrọ naa lai gbe wọn lọ teṣan.
 
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI