Níbi tí Emma, ọmọ 'Yahoo' ti fẹ́ẹ́ fi ìya rẹ̀ ṣòògùn owó làṣírí ti tú - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, September 17, 2021

Níbi tí Emma, ọmọ 'Yahoo' ti fẹ́ẹ́ fi ìya rẹ̀ ṣòògùn owó làṣírí ti tú


Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta ti tẹ gendekunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Emma, ẹni ti wọn lo n gbiyanju lati fi mama to bii lọmọ ṣoogun owo nijọba ibilẹ Okpe, ipinlẹ naa.
 
Ohun ti a gbọ ni pe ṣe ni Emma ranṣẹ pe mama rẹ, Oke sile ẹ to n gbe ladugbo Caroline, iyẹn lagbegbe Okuokoko lati jọ ọ loju.
 
Wọn ni bi mama naa ṣe de ile ọmọ rẹ lo ti n foju sọna lati ri ohun ti ọmọ naa fẹfi ya a lẹnu. Ṣugbọn si iyalẹnu, wọn ni ṣe ni Emma sare tilẹkun lẹyin, to si yi orin to n gbọ tẹlẹ soke.
 
Loju ẹsẹ ni wọn lo ki mama rẹ mọlẹ, to si fẹẹ fun mama naa lọrun pa, ko to fi ọbẹ yọ oju rẹ to fẹẹ lo fun etutu owo. Gbogbo asiko yii ni wọn sọ pe ko sẹni to gbọ ariwo 'ẹ gba mi' ti mama naa n pa niroyin ariwo orin to n lọ lọwọ.
 
Nipa oore ọfẹ Ọlọrun la gbọ pe mama naa fi jabọ lọwọ ẹ, to si sare lọ si oju ferese lati pariwo fun iranlọwọ, eyi gan an lo jẹ kawọn eeyan sare debẹ lati mọ nnkan to n ṣẹlẹ.
 

Iya ko to lilu fun Emma lọjọ naa, ti wọn tawọn eeyan dan iya fun un, ko to di pe wọn fa a le awọn ọlọpaa lọwọ. Ounjẹ la gbọ pe mama yii n ta.
 
 
Bright Edafe to jẹ agbẹnusọ fawọn ọlọpaa sọ pe oun ko tii gbọ si iṣẹlẹ naa, ati pe oun yoo ṣe iwadii rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI