Ẹ wojú bàbá arúgbó tó fún ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún lóyún l'Abẹ́òkúta, bẹ́ẹ̀ ló tún ṣẹ́yún fọ́mọ náà lẹ́ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, September 27, 2021

Ẹ wojú bàbá arúgbó tó fún ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún lóyún l'Abẹ́òkúta, bẹ́ẹ̀ ló tún ṣẹ́yún fọ́mọ náà lẹ́ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀


Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ baba agba radaradara kan, Jimọh Mutaliu ti wọn lo fun ọmọ ẹgbẹ rẹ, ọmọ ọdun mẹrindinlogun loyun niluu Abẹokuta, to si tun ti ṣẹyun fọmọ naa lẹẹmeji ọtọọtọ ri.

Jimọh, ẹni ọdun mejilelaadọta {52} ni AWIKONKO gbọ pe o ti pẹ to ti n ko ibasun fọmọ naa, ti a fi orukọ bo laṣiri, lai jẹ ki ẹnikẹni mọ si.
 
Wọn ni ṣe lo maa pe ọmọ yii bi ẹni to fẹẹ ran-an niṣẹ, igba ti ọmọ yii ba si de, ni yoo kii mọlẹ, ti yoo si ko ibasun fun un karakara.
 
Ẹẹmeji ọtọọtọ ti wọn lọmọ naa loyun mọ Jimọh lọwọ la gbọ pe o mu lọ sọdọ nọọsi kan lati ṣẹ awọn oyun naa fun un.
 
Wọn ni oyun ẹlẹẹkẹta yii lo tu aṣiri iṣẹ ibi ti Jimọh ti n ṣe si ara ọmọ ọhun, nigba ti wọn sọ pe baba rẹ lo ṣakiyesi pe ọmọ oun ti loyun, to si beere ẹni to fun un loyun.
 
Ọmọ yii lo jẹwọ pe Jimọh lo fun oun loyun, to si ti ṣẹyun foun lẹẹmeji tẹlẹri, ṣugbọn toun ko mọ pe oun yoo tun pada loyun.
 
Baba yii ko fi ọrọ naa falẹ rara to fi gba teṣan ọlọpaa Adatan lọ lati lọ fi to wọn leti. Loju ẹsẹ si lawọn ọlọpaa ti lọ gbe Jimọh nibi to wa.
 
Igba to de teṣan naa lo jẹwọ pe lotitọ ni, ati pe iṣẹ eṣu ni iwa toun hu naa, fun idi eyi, o bẹbẹ pe ki wọn forijin oun.
 
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Edward Awolọwọ Ajogun ti paṣẹ pe ki wọn tare Jimọh si ẹka ileeṣẹ wọn to n ri si iwa ọran dida lati tubọ ṣe iwadii rẹ finnifinni, ko to di pe wọn foju rẹ ba ile-ẹjọ.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI