Ilé méjìlélógún làwọn eléyìí digun jà lólè láàárín oṣù mẹ́ta kí ọwọ́ tóó tẹ̀ wọ́n - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, September 27, 2021

Ilé méjìlélógún làwọn eléyìí digun jà lólè láàárín oṣù mẹ́ta kí ọwọ́ tóó tẹ̀ wọ́n


'Tiwa ba wa' lọrọ abamọ to jade lẹnu awọn gendekunrin mẹta ti ẹ n wo oju wọn yii,
Kalifa Mustapha, ọmọ ogun ọdun; Tumba Abubakar, ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn; ati Faisal Abdullahi, toun jẹ ọmọ ọdun mọkanlelogun nigba tọwọ palaba wọn segi nibi ti wọn ti lọ digun jale.
 
Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu yii la gbọ pe okete wọn ko raaye bo iru mọ ọlọdẹ awọn ọlọpaa lọwọ nigba ti aṣiri wọn tu sita.
 
AWIKONKO gbọ pe meje ni awọn afurasi ọdaran yii, ti wọn jọ n digun jale kaakiri ipinlẹ Adamawa, ṣugbọn ti awọn mẹrin yooku ti juba ehoro ni kete ti aṣiri wọn tu.
 
Wọn ni ṣe lawọn eeyan yii n ti ojule de ojule lati ja awọn araalu lole, ti a si gbọ pe ile ti ko din ni mejilelogun ni wọn ti digun ja lole laaarin oṣu mẹta.

Eyi ti wọn lọ ṣe gbẹyin yii lo koba wọn, ti aṣiri fi tu sita.
 
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa, Mohammed Barde ti paṣẹ pe ki iwadii kikun bẹrẹ lori wọn lati le jẹ ki ọwọ tẹ awọn yooku wọn ti wọn ti salọ, ki wọn si le foju winna ofin ijọba pẹlu ẹsun ọdaran.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI