Ẹ̀bẹ̀ ni mo bẹ̀, ẹ má fi orúkọ mí ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn Yorùbá Nation mọ́ - Ìgbòho pariwo síta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, September 17, 2021

Ẹ̀bẹ̀ ni mo bẹ̀, ẹ má fi orúkọ mí ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn Yorùbá Nation mọ́ - Ìgbòho pariwo síta


Olori ẹgbẹ ajijangbara ilẹ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeniyi Adeyẹmọ, ti awọn eeyan tun mọ si Sunday Igboho ti rawọ ẹbẹ si gbogbo awọn ololufẹ rẹ kaakiri agbaye wi pe ki wọn ma ṣe fi orukọ oun ṣe iwọde ominira ilẹ Yoruba mọ.
 
Ọjọbọ, Tọside ana ni Oloye Sunday Igboho sọrọ yii jade wi pe kawọn eeyan yee fi orukọ oun ṣe iwọde ifẹhonuhan yala ti alalaafia ni, tabi ti tabi oniruuru ifẹhonuhan yoowu.
 
Ninu atẹjade ti agbẹjọro Igboho, Yọmi Alliyu fi sita lo ti sọ pe ọkunrin naa ti ṣe ikilọ fawọn eeyan, to si ni kawọn eeyan dide lorukọ ara wọn lati fi beere fun ominira ti wọn n fẹ, ki wọn si dẹkun lati maa lo orukọ oun.

Bẹẹ lo tun sọ pe ki ẹnikẹni ma ṣe da wahala silẹ, tabi uwa jagidijagan, tabi kọju ija sawọn agbofinro lakooko ti wọn ba n fẹhonu wọn han lati ja fun ominira ilẹ Yoruba ti wọn n fẹ.

"Ohun gbogbo ni akoko wa fun. Oloye Sunday Adeyemo Igboho Oosa bọwọ fun awọn to wa paayan danu ninu ile ẹ lọjọ kinni, oṣu keje, ọdun 2021.

"Fun idi eyi, ọkunrin naa ti ṣe ikilọ wi pe ki wọn ṣe gbe iwọde kankan kalẹ lorukọ oun fun igba ati akoko ti ẹnikẹni ko ti i mọ. Bẹẹ lo tun sọ pe ki wọn bọwọ fun mọlẹbi oun lati ma ṣe pe mama oun jade fun ohunkohun ti wọn ba fẹẹ ṣe nita gbangba.

"Lasiko yii, Igboho ko ni agbẹnusọ kankan nibikibi. Fun idi eyi, o n gba awọn eeyan lamọran lati ma ṣe gba awọn ọrọ ti wọn ba n sọ lorukọ oun gbọ.

"Ẹ jẹ ka bọwọ fun awọn oku. Ki ẹnikẹni ma ṣe lo doju kọ ibi yoowu tabi awọn agbofinro pẹlu ẹtanjẹ wi pe wọn n ja fun ominira ilẹ Yoruba."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI