Rex Ọláwoyè, àgbà olóṣèlú jáde láyé lójijì, làwọn èèyàn bá ń ṣe ìdárò rẹ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, September 17, 2021

Rex Ọláwoyè, àgbà olóṣèlú jáde láyé lójijì, làwọn èèyàn bá ń ṣe ìdárò rẹ̀


Iroyin ti ko dun mọ ẹnikẹni ninu ni ti iku Oloye Rex Olawoye, gbajugbaja agba oloṣelu nni to jade laye laipẹ.
 
Ọsibitu kan to wa niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara la gbọ pe baba naa dakẹ si lẹyin aisan rampẹ to kọlu lati bi ọjọ meloo kan sẹyin.
 
Laigba ti iroyin iku baba naa ti jade sita la gbọ pe awọn eeyan ti bẹrẹ sii fi atẹjade ibanikẹdun ranṣẹ sita, ti wọn si n sọ awọn ipa rere ti oloogbe naa ti ko nigba aye ẹ.
 
Gomina AbdulRahman AbdulRazaq nigba to n ṣapejuwe bi oloogbe naa ṣe wulo to nipinlẹ Kwara sọ pe baba naa jẹ igilẹyin ọgba fun jijawe olubori oun ninu idibo gomina to waye lọdun 2019.
 
O ni aṣiwaju ijijangbara to gbe iṣakoso Otogẹ de ijọba ni Oloogbe Rex Olawoye, to si ni bi ọrọ ba ṣe ri ni baba naa ṣe maa n sọ ọ lai fi ọrọ ẹlẹyamẹya ṣe.
 
AbdulRazaq sọ pe asiko ti ijọba ipinlẹ naa tubọ nilo rẹ gidigidi lo jade laye, ṣugbọn to sọ pe Ọlọrun lo mọ ohun gbogbo, to si le ṣe ohungbogbo, eyi to fi n ba gbogbo ẹgbẹ oṣelu APC ati mọlẹbi rẹ kẹdun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI