Ìjọba Kwara rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sìjọba àpapọ̀ lórí àwọn òpópónà tó bàjẹ́ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, September 10, 2021

Ìjọba Kwara rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sìjọba àpapọ̀ lórí àwọn òpópónà tó bàjẹ́


Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq l'Ọjọbọ, Tọside ana ti rawọ ẹbẹ sijọba apapọ lori awọn atunṣẹ awọn opopona to jẹ tijọba apapọ nipinlẹ naa, fun igbokegbodo ọkọ to ja geere.
 
AbdulRazaq lo rawọ ẹbẹ yii nigba to n ṣe ipade pọ pẹlu minisita fọrọ iṣẹ lorilẹ-ede yii, Babatunde raji Faṣọla.
 
Nibẹ ni Gomina AbdulRazaq ti sọ pe ki ijọba papaọ ma ṣe gboju fo awọn opopona to ti bajẹ gidi kaakiri ipinlẹ naa, eyi to ni wọn wa labẹ akoso ijọba apapọ, ti agbara ipinlẹ ko ka.
 
Ko ṣai dupẹ lọwọ awọn akanṣẹ opopona ti wọn ti ṣe sẹyin, ṣugbọn to tun sọ pe awọn opopona kan wa to jẹ pe ṣe ni wọn n ba mọto jẹ ni gbogbo igba, to si ni ki ijọba apapọ tete ṣe atnṣe, ko to pẹ ju.
 
Nigba toun naa n sọrọ, Babatunde Faṣọla sọ pe gbogbo eto lo ti to, nitori pe awọn opopona naa ti wa ninu eto iṣuna owo, to si ti di dandan lati ṣe ẹ.
 
Lara awọn to tun wa nibi ipade yii ni kọmiṣanna fọrọ iṣẹ, Rotimi Iliasu.
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI