Ileeṣẹ Sweet Estate gbàràdá nílùú Abẹ́òkúta, wọ́n ṣe bẹbẹ fáwọn oníbárà wọn lárà ọ̀tọ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, September 10, 2021

Ileeṣẹ Sweet Estate gbàràdá nílùú Abẹ́òkúta, wọ́n ṣe bẹbẹ fáwọn oníbárà wọn lárà ọ̀tọ̀


Ọjọ manigbagbe l'Ọjọbọ, Tọside ana, iyẹn ọjọ kẹsan, oṣu kẹsan, ọdun 2021 jẹ ninu itan igbesi aye awọn araalu Abẹokuta pẹlu bi awọn onibara ati awọn alagbata ileeṣẹ SWEET ESTATE to n ri si ọrọ ilẹ kaakiri ipinlẹ Ogun ṣe oriṣiriṣi ẹbun ṣe ifa jẹ. 
 
Nibi akanṣe eto ti ileeṣẹ naa maa n ṣagbatẹru ẹ lọdọọdun ni awọn ti ko din ni mẹẹdogun ti jẹ ẹbun ile ti owo rẹ ko din ni miliọnu mẹta, ẹbu ilẹ loriṣiriṣi, ati awọn ẹbun ohun elo inu ilẹ.
 
Arabinrin Okika Fidelia lo jẹ ẹbun ile nla ti owo rẹ ko din ni miliọnu mẹta ti ileeṣẹ SWEET ESTATE fi mọ riri awọn onibara ati alagbata wọn; nigba ti awọn bii Ọgbẹni Ọladele Ismail Ajao, Taiwo Kẹhinde, Alawọde Damọla atawọn miran jẹ ẹbun ile.
 
Ayọdele Ọladunjoye jẹ ẹbun firiiji; Kẹhinde Ogunbayọde jẹ ẹbun Rechargeable lamp; Akande Hammẹd Ṣeun jẹ ẹbun Iron; Onimọ-ẹrọ Okonjobo Edward ati Ojo Allen jẹ ẹbun Rechargeable fan; Ngube Immaculate ati Ọjẹwunmi Oluwaṣẹgun jẹ ẹbun; ti awọn miran si jẹ ẹbun jẹnẹretọ atawọn nnkan mi in ninu idije Raffle Draw ti wọn ṣe ni olu ileeṣẹ wọn to wa ni Aṣero nilu Abẹokuta.

Gbogbo awọn ti wọn jẹ ẹbun yii patapata ni wọn dupẹ lọwọ ileeṣẹ SWEET ESTATE, fun anfaani ti wọn n fi silẹ lati maa mọ riri awọn onibara ati alagbata

Yatọ si eyi, ileeṣẹ naa ti fi awọn mọto nla mẹrin ọtọọtọ lelẹ lati lẹ jẹ kawọn araalu jẹ igbadun ara ọtọ ti ko wọpọ. Awọn mọto naa lo jẹ ọfiisi alagbeka t wọn fẹ ko wa ni arọwọto awọn araalu, eyi to jẹ akọkọ iru ẹ ninu itan awọ ileeṣẹ to n ri sọrọ ile ati ilẹ nipinlẹ naa.
 
Nigba to n sọrọ, paapaa nipa awọn ipenija ti wọn ti n koju lati nnkan bi ọdun mẹrin sẹyin ti wọn ti da ileeṣẹ naa silẹ, Oloye Olumide Falọla to jẹ alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ SWEET ESTATE sọ pe oore-ọfẹ Ọlọrun lo n gbe awọn duro nitori pe ọpọ ojo lo ti rọ, ti ilẹ ti fa mu.
 
Ọkunrin naa ni lara awọn ti wọn fọkan tan nileeṣẹ naa gbabọdi fun wọn lati pa ileeṣẹ naa run, ti wọn si ko wọn si gbese nla ti wọn ko tii bọ ninu ẹ, eyi to sọ pe iyẹn ko ni kawọn ma ṣe ojuṣe wọn fawọn onibara ati alagbata wọn, nitori pe otitọ inu lawọn fi n ṣe ohun gbogbo.
 
Ninu ọrọ rẹ, Falọla sọ pe:
"Gbogbo ohun ti a n ṣe ni Ọlọrun mọ, beeyan ba patọ fun ẹnikan, ẹni ti wọn purọ fun le ma mọ, ṣugbọn Ọlọrun mọ. Bẹẹ si ni Ọlọrun maa san an fun onikaluku gẹgẹ bi iṣẹ ọwọ rẹ.

"Mo n fi asiko yii rawọ ẹbẹ si gbogbo awọn ti a ba ti ṣẹ wi pe kí wọn dariji wa. La ti nnkan bi oṣu mẹsan sẹyin lati nnkan koju awọn iṣoro kọọkan, nitori pe lara awọn ti a ko mọra dalẹ wa.

"Awọn naa si ni wọn ko wa si gbese nla. Gbese naa ṣe akoba pupọ fun wa, eyi to fẹẹ dabi ẹni pe inu awọn onibara wa ko dun si.

"Gbogbo awọn idaduro ti a ni, kii ṣe ohun ti o dun mọ wa ninu, nitori pe awọn to jẹ wa lẹsẹ ni wọn fẹẹ ki ileeṣẹ wa parun, ṣugbọn ti Ọlọrun mu wa bori.

"Lara awọn gbese ti a jẹ ni ileeṣẹ kan ti wọn gbe iṣẹ fun wa, owo iṣẹ naa ko din ni ọgọjọ miliọnu (N160m) naira. Wọn ti fun wa ni owo, miliọnu mọkanlelọgọta naira. 

"Nigba ti wahala naa bẹrẹ, awọn to gbe iṣẹ fun wa sọ pe ka da gbogbo owo naa pada fun wọn, eyi si la n san pada loṣooṣu. Ko si nnkan meji to fa, bi ko ṣe pe awọn to jẹ wa lẹsẹ lo tun lọ ba orukọ ileeṣẹ wa jẹ.

"Ọlọrun ti ran wa lọwọ, nitori pe bi mo ṣe n ba a yin sọrọ yii, a ti san ogoji miliọnu pada ninu ẹ. Iṣoro yii ati awọn miran ti a ko le sọ tan la n koju, ti a ko si tun ja awọn onibara wa kulẹ.

"Ohun ti ọpọ awọn eeyan ro ni pe a ko le la iṣoro yii ja, ati pe laaarin ọdun mẹrin sẹyin ti a bẹrẹ, Ọlọ́run n ran wa lọwọ kọja sisọ.



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI