Ìlú Abẹ́òkúta fẹ́ẹ́ gbàlejò nlá: Ilé-iṣẹ́ Ọmọ Lámúrúdu fẹ́ẹ́ ṣayẹyẹ ìdásílẹ̀ ọdún karùn-ún láràọ̀tọ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, September 30, 2021

Ìlú Abẹ́òkúta fẹ́ẹ́ gbàlejò nlá: Ilé-iṣẹ́ Ọmọ Lámúrúdu fẹ́ẹ́ ṣayẹyẹ ìdásílẹ̀ ọdún karùn-ún láràọ̀tọ̀


Gbogbo eto lo ti fẹẹ pari patapata bayii, fun ayẹyẹ ọdun karun-un ti wọn da ileeṣẹ iroyin nni, Ọmọ Lamurudu Media silẹ, nibi ti awọn eeyan pataki-pataki yoo ti peju pesẹ sibẹ.

Ileeṣẹ Ọmọ Lamurudu Media jẹ ileeṣẹ iroyin to n gbe aṣa, iṣe ati iṣẹdalẹ ilẹ Yoruba larugẹ kaakiri agbaye, ti wọn si ti gba oriṣiriṣi aami ẹyẹ nipa akitiyan wọn.

Ninu atẹjade ti alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ naa, Ọmọọba Ismail Alabi fi sita laaarọ oni, Ọjọbọ, Tọside, ọgbọn ọjọ, oṣu kẹsan, lo ti jẹ ko di mimọ pe ọjọ keje, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022 ni ayẹyẹ ọdun karun-un naa yoo waye.

Ọmọọba Alabi sọ pe gbọngan ayẹyẹ ti LUKJIM, to wa ni Olomore, nilu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun ni ayẹyẹ ọhun yoo ti waye, pẹlu alakalẹ eto ọlọkan-o-jọkan.Lọjọ naa ni wọn yoo tun ti ṣe ikojade magasiini tuntun, eyi ti wọn yoo ti maa ṣe afihan awọn ipenija, adojukọ ati awọn oriṣiriṣi akanṣe iṣẹ ti wọn ti ṣe nipa igbelarugẹ aṣa Yoruba.

Bo tilẹ jẹ pe a ko tii gbọ boya wọn yoo lo aṣọ ẹgbẹjọda lọjọ naa, sibẹ a gbọ pe awọn agbaagba nidii iṣẹṣe Yoruba, awọn ọba alaye, ati awọn ọtọkulu lawujọ ni wọn yoo wa nibẹ lọjọ naa.
 
Fun alaye tabi ibeere lẹkunrẹrẹ, tabi lati ṣe ipolowo ọja yin ninu magasiini naa, ẹ le pe 08118176021
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI