Òndó: Wọ́n ju Mohammed ati Tósìn sẹ́wọ̀n ọdún mọ́kànlélógún nítorí adìẹ tí wọ́n jí gbé - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, September 30, 2021

Òndó: Wọ́n ju Mohammed ati Tósìn sẹ́wọ̀n ọdún mọ́kànlélógún nítorí adìẹ tí wọ́n jí gbé


Ile-ẹjọ giga tipinlẹ Ondo, eyi to wa niluu Akurẹ ti sọ awọn meji kan, Salifu Muhammed ati Akọmọlafẹ Tosin sẹwọn ọdun mọkanlelogun gbako lori ẹsun idigunjale ti wọn fi kan wọn.

AWIKONKO gbọ pe owo ti ko din ni ẹgbẹrun lọna aadọjọ (N150,000) naira, ati awọn nnkan mi-in bii epo isebẹ, adiẹ abbl lawọn mejeeji jigbe lọdun 2014.

Agbegbe kan ti wọn pe ni Ayejori-Okeoge, to wa ni Akurẹ la gbọ pe wọn ti digunjale yii, pẹlu awọn yooku wọn, ti wọn lawọn ti na papa bora.

Gẹgẹ bi igbimọ to fẹsun kan wọn, eyi ti Wale Maniṣile lewaju rẹ ṣe ṣalaye niwaju ile-ẹjọ, wọn ni ọwọ obinrin kan to n jẹ Opetu Juliana ni wọn ti digun gba owo naa.

Juliana naa funra rẹ, nigba to n sọrọ niwaju ile-ẹjọ sọ pe oun ko da ẹnikẹni mọ ninu awọn adigunjale naa, nitori pe ṣe ni wọn da aṣọ boju wọn, ṣugbọn to loun gbọ pe awọn tọwọ tẹ yii jẹwọ ni teṣan ọlọpaa wi pe awọn ni wọn wa labẹ aṣọ iṣẹ ibi ọjọ naa.

Ẹnikan to pe orukọ ara rẹ ni Kayọde Afọlabi, nigba toun naa n jẹri tako wọn sọ pe, oun wa lara awọn to rọwọ to wọn, to si ni yatọ si owo ti wọn gba, wọn tun ji epo isebẹ, kokoo ati adiyẹ mejila gbe salọ.

Awọn mejeeji lati ẹnu awọn agbẹjọro wọn, Ọladapọ  ati Ilesanmi Ikuemenisan sọ pe awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.
 
Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Onidajọ Williams Ọlamide sọ pe awọn ẹri toun ri gba fidi rẹ mulẹ pe loootọ lawọn mejeeji ṣẹ ẹṣẹ naa, to si ni ki wọn lọ fi ẹwọn ọdun meje gbara lori ẹsun ipawọpọ ṣebi, ati ẹwọn ọdun mọkanlelogun lori ẹsun idigunjale.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI