Ìpínlẹ̀ Kwara yóò di apẹ̀rẹ̀ oúnjẹ fún Nàìjíríà láìpẹ́ - Gómìnà - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, September 13, 2021

Ìpínlẹ̀ Kwara yóò di apẹ̀rẹ̀ oúnjẹ fún Nàìjíríà láìpẹ́ - Gómìnà


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq sọ pe awọn ti ya obitibiti ilẹ silẹ fun iṣẹ agbẹ ati ọgbin, eyi to le mu ki ounjẹ pọ rẹpẹtẹ fawọn ipinlẹ naa ati agbegbe ẹ.
 
Agbegbe kan ti wọn pe ni Agbeyangi la gbọ pe ijọba ipinlẹ naa ti ya ilẹ ti ko din ni ọgọrun-un ẹkita {100 hectares} ni ijọba sọ pe awọn ya silẹ lati fi ṣe ọgba idakosi tijọba apapọ, iyẹn Federal Government Farm Estate.
 
O ni gbogbo afojusun iṣakoso yii ni bi ounjẹ yoo ṣe pọ lọpọ yanturu, ti yoo si sọ ipinlẹ ọhun di apẹrẹ ounjẹ fun orilẹ-ede Naijiria, eyi ti yoo jẹ anfaani ipee iṣẹ fawọn ọdọ ati awọn obinrin.
 
Opin ọsẹ ti a ṣẹṣẹ lo tan yii ni Gomina AbdulRazaq sọrọ naa lakooko to gba akọwe ileeṣẹ to n ri sọrọ ilẹ fun iṣẹ agbẹ, National Agricultural Land Development Authority (NALDA), Ọmọọba Paul Ikonne lalejo, ẹni to wa ṣabẹwo si akanṣe iṣẹ agbe tijọba apapọ ṣagbatẹru nilu Agbeyangi, ijọba ibilẹ Ilorin East.
 
Nibẹ ni gomina AbdulRazaq gbe oriyin fun Aarẹ Muhammadu Buhari fun bi ko ṣe gbagbe ọrọ iṣẹ agbẹ ati ọgbin, to si n wa gbogbo ọna lati mu idagbasoke ba a.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI