Haaaa! Wọ́n ní ara Ìyábọ̀ Òkò, àgbà òṣèrébìnrin nnì kò yá gidi o, owó ìtọ́jú ni wọ́n n wá báyìí - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, September 12, 2021

Haaaa! Wọ́n ní ara Ìyábọ̀ Òkò, àgbà òṣèrébìnrin nnì kò yá gidi o, owó ìtọ́jú ni wọ́n n wá báyìí


Adura alaafia ati ẹmi gigun lawọn oṣere tiata kaakiri orilẹ-ede Naijiria n gba fun agba oṣerebinrin nni, Iyabọ Oko, lori bi wọn ṣe lo dubulẹ aisan lojiji.

Iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ fi ye wa pe o ti le lọdun mẹwaa ti Iyabọ Oko ti wa lori idubulẹ aisan, to jẹ pe ṣe ni wọn n gbe kaakiri.

A gbọ pe awọn ọmọ re ti gbe e lọ si oriṣiriṣi ọsibitu fun itọju, ṣugbọn to jẹ pe pabo lo n ja si, idi ree ti wọn tun fi gbe e lọ tọju loke okun.

Ọpọ owo ni iroyin fi to wa leti wi pe awọn ọmọ ati mọlẹbi Iyabọ Oko ti na lori aisan to dee mọlẹ naa. Koda, wọn ni foniku-fọladide ni aisan to n ṣe e, to ba gbadun lonii, ara rẹ yoo ya lọla.

Bi a ṣe n sọrọ yii, wọn ni aisan naa ti kọja ohun ti agbara awọn ọmọ rẹ le ka mọ, eyi lo jẹ ki wọn pariwo sita fun iranlọwọ owo ti wọn le fi tọju ẹ, ko ma ba a ku.

Folukẹ Daramọla toun naa jẹ gbajumọ oṣere lo gbe iroyin yii sita laipẹ yii, nibi to ti n rawọ ẹbẹ iranlọwọ owo si awọn ẹlẹyinju aanu lorilẹ-ede yii, ati kaakiri agbaye.

Daramọla sọ pe ajọ Passion Against Rape and Abuse, PARA toun da silẹ ti ṣe ọpọlọpọ iranwọ lati bi ọdun marun-un sẹyin, ṣugbọn to ni agbara ko ka mọ bayii.

O wa tun fi kun ọrọ rẹ wi pe ko si iye owo to kere ti awọn eeyan ko le fi ṣe aanu fun Iyabọ Oko lati lee gbe e dide lori idubulẹ aisan naa.

Lati fi owo ranṣẹ:
Passion Against Rape and Abuse Foundation
Zenith Bank 
1016578835

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI