Iṣẹ́ kín ni gómìnà gbàtúẹ̀yọ̀ Abíọ́dún n ṣe l'Ógùn? - Ṣẹ́gun Ṣówùnmí sọ̀kò ọ̀rọ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, September 25, 2021

Iṣẹ́ kín ni gómìnà gbàtúẹ̀yọ̀ Abíọ́dún n ṣe l'Ógùn? - Ṣẹ́gun Ṣówùnmí sọ̀kò ọ̀rọ̀


Agbẹnusọ fun Alaaji Atiku Abubakar, oludije sipo Aarẹ orilẹ-ede Naijiria lọdun 2019, Oloye Ṣẹgun Ṣowunmi ti sọ pe gomima gbatuẹyọ lasan ni Dapọ Abiọdun pẹlu ijọba radarada to n ṣe le awọn araalu lori.

Ṣẹgun Ṣowunmi ninu ọrọ to kọ sori ikanni ayelujara ti fesibuuku rẹ lonii, ọjọ Satide, Abamẹta lo ti sọ pe gomina Abiọdun ko mọ nnkan to n ṣe mọ rara, ati pe ijọba ko ye e.

O nigba toun ṣe agbeyẹwo bi nnkan ṣe n lọ, oun ṣakiyesi pe awọn ipinlẹ kan ti wọn ti wa lẹyin ipinlẹ Ogun lakooko ijọba ana ni wọn ti lewaju bayii nipa eto ọrọ aje ṣiṣe.

Ninu ọrọ rẹ, Ṣẹgun Ṣowunmi sọ pe

"O jinlẹ ju bẹẹ lọ, ẹ wo Kaduna, wọn ṣẹṣẹ pari Kadinvest 6.0 ni. Ẹ wo Akwa Ibom, wọn ṣẹṣẹ pari ile alaja nla kan ti wọn pe ni Smart City Tower ni, ẹ wo Ọyọ, wọn ti n gbaradi lati ṣe afihan igba ọtun ninu eto iṣẹ agbẹ ati ọgbin nibi ipatẹ ọja agbẹ agbaye ti International Agric Summit.

"Ẹ beere lọwọ gbatuẹyọ gomina ipinlẹ Ogun wi pe kin ni wọn fẹẹ fi ṣe afihan fun agbaye? Ṣe ohun to n ṣagbelarugẹ irin ajo afẹ ni, ṣe ti owo ti wọn n pa wọle to lọ soke ni? Ṣe ti eyi to n gbe awọn olokoowo kekeeke lọ soke ni, abi kin ni wọn m ṣe gan-an?"


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI