Ọwọ́ tẹ Ismail, ọmọ ọdún márùndínlọ́gbọ̀n tó pa àbúrò rẹ̀ láti fí ṣe oògùn owo ní Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, September 25, 2021

Ọwọ́ tẹ Ismail, ọmọ ọdún márùndínlọ́gbọ̀n tó pa àbúrò rẹ̀ láti fí ṣe oògùn owo ní Kwara


Ọwọ ileeṣẹ eleto aabo Sifu Difẹnsi nipinlẹ Kwara ti tẹ gendekunrin, ọmọ ọdun marundinlọgbọn kan, Ismail Saliu lori bo ṣe ṣeku pa aburo rẹ, Azeez Saliu, ọmọ ọdun mẹrinla, pẹlu erongba lati fi ṣoogun owo.

AWIKONKO gbọ pe ṣe ni Ismail gbimọ papọ pẹlu babalawo kan, Ahmed Nkwe, ẹni ọdun mẹrinlelogoji ati Saliu Ahmed, ọmọ ọgbọn ọdun lati pa Azeez danu.

Wọn ni ṣe ni wọn tan Azeez lọ sinu igbo nla kan lọjọ kẹtala, oṣu yii, nibi ti Ismail ti dunbu ẹ bi ẹran Ileya.

Lara awọn ti wọn kofiri wọn nigba ti wọn sọ pe irisi wọn mu ifura dani la gbọ pe wọn ta ileeṣẹ Sifu Difẹnsi lolobo, ti wọn si sare lọ sibẹ.

A gbọ pe wọn ti pa Azeez, wọn si ti sin oku rẹ sinu igbo, koda, wọn ti n lọ sibi ti wọn ti fẹẹ ṣe etutu owo ko to di pe wọn dena de wọn.

Agbegbe kan ti wọn n pe ni Kosubosu nijọba ibilẹ Batutẹn, ipinlẹ Kwara niṣẹlẹ yii ti waye, gẹgẹ bi agbẹnusọ ileeṣẹ Sifu, Babawale Zaid Afọlabi ṣe sọ lonii.

Afọlabi sọ pe Ismail ti jẹwọ pe lotitọ lawọn pa Azeez lati fi ṣoogun owo, ṣugbọn to sọ pe iṣẹ eṣu ni, nitori ti ko mọ pe aṣiri maa pada tu.

O lawọn yoo ko gbogbo wọn lọ ọlọpaa lati tẹsiwaju iwadii wọn, to si loun nigbagbọ pe wọn yoo foju wọn ba ile-ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI