Lẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ọ́ jáde fásitì, Rukayat gbẹ́mì ara rẹ̀, ó tún ṣàlàyé ìdí tó fi gbé ìgbésẹ̀ náà - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, September 28, 2021

Lẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ọ́ jáde fásitì, Rukayat gbẹ́mì ara rẹ̀, ó tún ṣàlàyé ìdí tó fi gbé ìgbésẹ̀ náà


Bo tilẹ jẹ pe a ko tii le fidi iru iku to pa gendebinrin kan, tọjọ ori rẹ ko tii ju ọdun marundinlọgbọn lọ, Rukayat Rukayat Umar, ṣugbọn sibẹ, kayeefi nla gidi lọrọ iku rẹ ṣi n jẹ fun gbogbo awọn to mọ ọn, paapaa awọn mọlẹbi rẹ.
 
Iroyin to AWIKONKO lọwọ jẹ ko ye wa pe ṣe ni Rukayat gbe majele jẹ, eyi to jẹ ki wọn sare gbee lọ si ọsibitu lati doola ẹmi rẹ, ṣugbọn ti ẹpa ko pada boro fun un.
 
A gbọ pe Rukayat ṣẹṣẹ pari ẹkọ rẹ ni fasiti tilu Birnin Kebbi, nipinlẹ Kebbi. Koda, ẹka ikẹkọọ to nii ṣe pẹlu ọrọ oṣelu, iyẹn Political Science lo ti ṣetan, to si n reti ọjọ ti yoo lọ ṣe eto agunbanirọ rẹ.
 
Ọkan lara awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kwara, Ọnọrebu Saidu Baba Ahmed, ṣalaye pe adanu nla niku naa jẹ, paapaa fun mọlẹbi Rukayat, ati oun funra oun, nitori pe ọmọ lo jẹ soun.
 
Ahmed ṣalaye pe Rukayat ṣalaye awọn nnkan to n koju foun lori bẹẹdi to wa lọsibitu, nibi to ti n jẹ irora, eyi to jẹ kawọn eeyan nigbagbọ pe ṣe lo gbe majele jẹ lati gbẹmi ara rẹ.
 
Ninu ọrọ ti Ọnọrebu Ahmed sọ, o ni Rukayat sọ pe awọn iṣoro toun n koju lakooko yii, kọja awọn iṣoro toun ti koju sẹyin, iyẹn lasiko toun wa nile-ẹkọ lati gba iwe ẹri BSc.
 
"Ọjọ naa yọ funfun, gẹgẹ bi awọn ọjọ yooku, ko si si apẹẹrẹ wi pe alẹ ogunjọ, oṣu kẹsan, 2021, yoo sọ fun mi pe maa ri, maa tun gbọ iroyin to banilọkanjẹ lojiji nipa iku ọmọ mi, Ruqaiyatu Umar.
 
"Mo ṣi le gbọ kango-kango ọrọ to sọ gbẹyin, nigba ti mo lọ ṣabẹwo sii lọsibitu ni nnkan bi aago mẹwaa aabọ alẹ. "Baba zulu" gẹgẹ bo ṣe maa n pe mi, 'Ko si iye ohun ti mo n la kọja lasiko yii, ti a le fi we awọn eyi ti mo la kọja lasiko ti mo n kẹkọọ lati gba iwe ẹri BSc. mi. Ni bayii, mo ti ṣetan fun agunbanirọ.
 

"'Ọgbẹ ọkan ti baba ati iya mi la kọja lati rii pe ala rere wọn si imuṣẹ lo tun maa peleke sii. Emi pẹlu wọn le ma jọ jeere iṣẹ ti a laagun fun.'
 
"O si mi eemi ijinlẹ. Mo gba a lamọran wi pe ko duro ṣinṣin, ko si ma ṣe sọ ireti nu. Eyi ni ohun ti emi pẹlu rẹ jọ sọ gbẹyin. Ki Ọlọrun ko tẹ ẹ si afẹfẹ rere, ko si fun awọn mọlẹbi rẹ ni ọkan lati gbe iṣẹlẹ naa kuro lọkan. Amin."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI