Lọ́jọ́ ìgbéyàwó! Ìdílé kan àti àwọn àlejò parun lójijì - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, September 28, 2021

Lọ́jọ́ ìgbéyàwó! Ìdílé kan àti àwọn àlejò parun lójijì


Ariwo ikunlẹ abiyamọ lo gba ẹnu awọn eeyan nipinlẹ Rivers lọjọ Aiku, Sannde, ijẹta nigba ti wọn sọ pe awọn idile kan parun lakooko ti wọn lọ sibi ayẹyẹ igbeyawo ọkan lara mọlẹbi wọn.

Ohun ti a gbọ ni pe, awọn ti ko din ni mẹtala lo parun sinu ijamba ọkọ to waye nitosi agbegbe kan ti wọn pe ni Akpoku-Udufor, nijọba ibilẹ Etche, iyẹn lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu yii.

A gbọ pe Oloye kan, Oloye Ambrose Igbokwe Nwuzi lo n ṣe ayẹyẹ igbeyawo ibilẹ pẹlu iyawo kẹta to ṣẹṣẹ fẹ. Oju ọna ti wọn lawọn mọlẹbi ọkunrin naa pẹlu awọn alejo rẹ wa la gbọ pe wọn ti padanu ẹmi wọn sinu ijamba ọkọ to waye laaarin bọọsi elejo ati tirela nla kan.
 
Won ni agbegbe Afara nilu Etche lawọn eeyan naa ti kuro, ti wọn si n lọ si ilu Imo to sunmọ wọn lati ṣayẹyẹ naa.
 
Ko tii ju ọgbọn iṣẹju lọ si asiko ti wọn gbera, ti wọn kagbako ijamba naa lori ere aapajude. A gbọ pe ṣe ni bọọsi wọn gbokiti, eyi to mu kawọn eeyan farapa yannayanna, ti awọn ti ko din ni mẹtala si sọda sọrun alakeji.
 
Aburo ati awọn mọlẹbi ọkọ iyawo, to fi mọ awọn alejo ni wọn wa ninu bọọsi yii.
 13 wedding guests including groom

13 wedding guests including groom

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI