Mo nígbàgbọ̀ wí pé Nàìjíríà yóò dára jù báyìí lọ - Adérìnókùn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉThursday, September 30, 2021

Mo nígbàgbọ̀ wí pé Nàìjíríà yóò dára jù báyìí lọ - Adérìnókùn


Alaṣẹ ati oludari ajọ alaanu
Olumide and Stephanie Aderinokun Foundation, Ọnọrebu Olumide Aderinokun ti sọ pe oun nigbagbọ gidigidi wi pe orilẹ-ede Naijiria ṣi maa dara ju ipo to wa lasiko yii lọ, ti yoo si di orilẹ-ede tawọn eeyan n foju sọna fun lati ọgọta ọdun sẹyin.

Ọnọrebu Aderinokun lo sọrọ yii nibi ipade ti ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorilẹ-ede yii, ẹka tipinlẹ Ogun ṣe niluu Abẹokuta, lati fi saami ayẹyẹ ọgọta ọdun ti Naijiria ti gba ominira.
 
Lakooko to n bawọn akọroyin sọrọ, Aderinokun sọ pe onikaluku lo ni ojuṣe to yẹ ki wọn, eyi to le mu ki Naijiria ri bi awọn eeyan ṣe n fẹ, to si tun gbawọn oṣiṣẹ lamọran lati darapọ mọ oṣelu, bi wọn ba n fẹ ilọsiwaju.
 
"Ni ero ọkan mi, mi o ni iyemeji wi pe orilẹ-ede yii ko le di ohun tawọn araalu n foju sọna fun lati ọgọta ọdun sẹyin. A ni lati maa gbadura, ka si nii lọkan wi pe ẹni ti a ba ti dibo fun, ti ko ṣe ojuṣe rẹ bo ti tọ, ko nilo ka tun pada dibo fun wọn.
 
"Awọn oṣiṣẹ naa gbọdọ darapọ mọ oṣelu, nitori pe oṣelu lo n ṣatọnu awọn nnkan to n ṣẹlẹ si gbogbo wa ni Naijiria. Gbogbo ohun ti a fẹẹ jẹ lọjọ iwaju, nipa oṣelu ni, fun idi eyi, a ni lati ba wọn ṣe e. Mo si nigbagbọ pe Naijiria yoo dara ju bayii lọ."
 
Bakan naa lo gba awọn araalu lamọran lati gbaruku ti ijọba apapọ lati le jẹ ki Naijiria ni idagbasoke to yọranti.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI