Nítorí àwọn ọlọ́pàá tó pè lólè, wọ́n ju Hassan sẹ́wọ̀n ọdún méjì gbáko - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, September 22, 2021

Nítorí àwọn ọlọ́pàá tó pè lólè, wọ́n ju Hassan sẹ́wọ̀n ọdún méjì gbáko


Ile-ẹjọ to n gbọ ẹsun ọdaran nilu Yola, ipinlẹ Adamawa, ti ju gendekunrin ọmọ ọdun marundinlọgbọn kan, Bala Hassan sẹwọn ọdun meji gbako pẹlu iṣẹ aṣkara lori ẹsun wi pe o pe awọn ọlọpaa ni ole ati alọnilọwọgba.
 
Ojọ Iṣẹgun, Tuside ana ni ọga ọlọpaa ipinlẹ naa, Adamu Alhaji wọ Hassan lọ siwaju ile-ẹjọ naa ti Onọrebu Nuhu Garta lewaju fun.
 
Wọn ni ṣe ni Hassan sọ pe gbogbo awọn ọlọpaa ẹkun Jimeta ni ole ati alọnilọwọgba. Wọn ni Hassan sọ pe o tẹ oun lọrun lati ku danu, ju koun lọ darapọ mọ iṣẹ ọlọpaa nitori pe ọdaran ni wọn.
 
Onidajọ Nuhu Musa Garta nigba to n gbe idajọ naa kalẹ paṣẹ pe ki Hassna lọ fi ẹwọn ọdun meji gbako gbara, tabi ko san ẹgbẹrun lọna aadọta naira gẹgẹ bi owo itanran.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI